Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 29, Oṣù Keje 2026.
*Gbajugbaja onkowe àgbáyé nnì tí sọ pé àkókò ti tó láti parí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ lórí àwọn ìpànìyàn òṣèlú tó ga jùlọ ní Nàìjíríà
Nobel Laureate, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká ti rọ̀ Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinubu láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa ṣíṣí àwọn ẹjọ́ ìpànìyàn àti ìṣẹ́lẹ̀ ìpànìyàn tí a kò tíì yanjú ní Nàìjíríà padà.
Ṣóyínká ṣe ìpè yìí ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ní Freedom Park, Èkó, nínú ètò kan tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ “June 12: Romancing the Embers” láti ṣe ayẹyẹ Ọjọ́ Ìjọba Aláwàámàríwá.
NÍNÚ Ọ̀RỌ̀ RẸ̀, Ó TẸNU MỌ́ ỌN PÉ KÍ ÌJỌBA ṢE ÌWÁDÌÍ TUNTUN SÍ :
Dele Giwa – Akọ̀ròyìn olókìkí tí wọ́n pa nípasẹ̀ lẹ́tà bọ́mbu ní ọdún 1986
Olóyè Bọ́lá Ige – Minisita ètò ìdájọ́ tẹ́lẹ̀ tí wọ́n pa nílé rẹ̀ ní Ibadan ní ọdún 2001
Kudirat Abiola – Akọni June 12 tí wọ́n yìnbọn pa ní Èkó ní ọdún 1996
Gẹ́gẹ́ bí Ṣóyínká ṣe sọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmọ̀ràn àti ẹ̀rí ló wà tí a kò tẹ̀lé rí, àti pé àwọn ènìyàn kan mọ̀ọ́mọ̀ ba ìwádìí àtijọ́ jẹ́.
“A kò lè máa sọ pé a ń ṣe ayẹyẹ ìjọba aláwàámàríwá, kí a sì fi àwọn tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ wọn ra ìjọba náà sílẹ̀ lai ní ìdájọ́ òdodo. Àkókò ti tó láti fọ abọ́,” ni Ṣóyínká ṣe sọ.
Ìpè yìí wáyé ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí Ààrẹ Tinubu fún àwọn akọni June 12 ní ọlá orílẹ̀-èdè 68. Ṣóyínká dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ fún ọlá náà, ṣùgbọ́n ó sọ pé àwọn wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀gbá tókù lórí ètò ìdájọ́ Nàìjíríà tí ó gbọdọ̀ parẹ́.
Ó sì yà ọlá orílẹ̀-èdè tí òun fúnra rẹ̀ gbà sí iranti ọ̀rẹ́ rẹ̀, Dr. Beko Ransome-Kuti, akọni ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.
