Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 8, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Dr. Kunle Samson Adegbite (TWINDAD), olùdíje fún ipò Aṣojú ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀ fún Ogbomoso North, Ogbomoso South àti Oriire, ti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì mìíràn láti fìdí múlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ sí ààbò àti ìdàgbàsókè àwùjọ̀ wa.
Lónìí, ó fi mọ́tò alùpùpù (Yamaha) tuntun ṣe ẹ̀bùn fún ẹgbẹ́ Irú Ẹkun Security, ẹ̀ka Ogbomoso, láti mú kí iṣẹ́ wọn túbọ̀ lágbára àti láti mú kí ìrìnàjò wọn rọrùn nínú àwọn àdúgbò wa.

Aṣáájú náà fi iṣẹ́ náà lé ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti fi mọ́tò náà lé Chief Sunday Igboho, Olùdásílẹ̀ àti Alákóso Irú Ẹkun Security ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Dr. Adegbite sọ pé:
“Mo gbà gbọ́ gidigidi pé àṣáájú kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìlérí òṣèlú nìkan. Ó yẹ kí a fi hàn nípasẹ̀ àwọn ìgbésẹ̀ gidi tí ó ń dáhùn sí àìní àti ìṣòro àwọn ará wa. Ààbò jẹ́ ojúṣe gbogbo wa. Nítorí náà, ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí wọ́n fi ara wọn jìn láti dáàbò bo àwùjọ̀ wa jẹ́ ojúṣe tí ó ṣe pàtàkì sí mi pẹ̀lú.”
Ó tún ké sí àwọn aṣáájú àwùjọ, àwọn tó ń bójú tó ààbò, àwọn ilé-iṣẹ́, ẹgbẹ́ àjọ, àwọn aṣáájú òṣèlú àti gbogbo ẹni rere láti darapọ̀ mọ́ oún nínú mímú ètò ààbò le sí i ní orílẹ̀-èdè wa.

“A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀ láti kọ́ àwùjọ tí àwọn ènìyàn wa lè gbé, ṣiṣẹ́, kí wọ́n sì lè ní ìlọsíwájú nínú àlàáfíà àti ààbò. Èyí ni irú àṣáájú tí mo gbà gbọ́ nínú rẹ̀ — àṣáájú tí ó ń gbọ́, tí ó ń dáhùn, tí ó sì ń gbé ìgbésẹ̀. Iṣẹ́ náà ṣì ń tẹ̀síwájú.”
Dr. Kunle Samson Adegbite (TWINDAD)
Olùdíje NDC fún Ogbomoso North, South & Oriire Federal Constituency
Ìṣẹ́ fún Aráyé. Ìfarajìn sí Ìdàgbàsókè.

One thought on “KUNLE ADEGBITE GBÉ IGBESẸ OTUN LÁTI S’ATILEYIN FÚN ÈTÒ ÀBÒ”