Orisun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Rafiu Badmus, Osogbo |Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 30, Oṣu Keje 2026
*Yóò rọ́pò Mohammed Abba tó ti fẹ̀yìntì; ṣe ìlérí ààbò tó péye
Ọlọ́paà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti ní olórí tuntun. CP Ibrahim Gotan ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà Ọlọ́paà tuntun fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Ó rọ́pò CP Mohammed Umar Abba tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ̀yìntì kúrò nínú iṣẹ́ ọlọ́paà. Ìkéde yìí wá nínú àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ ọlọ́paà ìpínlẹ̀ náà, DSP Abiodun Ojelabi fi síta ní ọjọ́ Ìsẹ́gun ní Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ náà, Osogbo. 4444
KÍ NÍ A MỌ̀ NÍPA RẸ̀?
CP Gotan jẹ́ ọmọ Ìjọba Ìbílẹ̀ Pankshin ní Ìpínlẹ̀ Plateau. Ó gboyè B.Sc nínú Sociology ní Yunifásítì Ahmadu Bello, Zaria, ó sì dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ọlọ́paà Nàìjíríà ní oṣù karùn-ún ọdún 1992 gẹ́gẹ́ bí Cadet Assistant Superintendent.
Ó jẹ́ Kọmíṣọ́nà ẹlẹ́kẹjọdínlọ́gbọ̀n tí yóò ti ṣe ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
NÍNÚ Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́KỌ́ RẸ̀ , Ó ṢE ÌLÉRÍ LÁTI:
Mú ààbò àti àlàáfíà pọ̀ sí i ní gbogbo Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
Bá àwọn oníròyìn àti àwọn ará ìlú ṣiṣẹ́ pọ̀
Rí i dájú pé ọlọ́paà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láìṣe ojúsàájú
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ń retí pé ìgbà rẹ̀ yóò mú ìdàgbàsókè bá ààbò ní Osun, pàápàá jùlọ bí ètò ìdìbò ọdún 2026 ṣe ń súnmọ́lé.
