Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku 30, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Ní báyìí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu tí lọ lo ìsinmi lẹ́nu iṣẹ fún tí ọdún yìí ni ilẹ̀ Europe, ṣùgbọ́n ìlú London níbi àkọ́kọ́ tí yóò kọkọ́ gunle sì, òwúrọ̀ onii ọjọ Aiku ọgbọ́n’jọ ni komisanna ètò ìròyìn Bayo Onanuga fi síta pé Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu yóò gun ọkọ létí lọ sí orile-ede Europe loni fún ìsinmi lẹ́nu iṣẹ.
Ṣugbọn ìròyìn to tí ilé ìjọba l’Abuja jáde kò fìdí rẹ múlẹ̀ pé enikan bai ni yóò máa délé de Ààrẹ Tinubu.
Ṣugbọn òun ti àwọn èèyàn ń bere bai nipe taa ni yóò máa pàṣẹ orile-ede yii lásìkò ìsinmi Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, eyii ni ó jẹ ki a mú wá sí ìrántí yín, òun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn.
*Tani o n ṣakoso Nàìjíríà bayii?
Ìròyìn AANTV sọ pe àlàyé lati ọwọ́ Bayo Onanuga kò sọ bóyá Igbákejì Ààrẹ Kashim Shettima yóó gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Adelé Ààrẹ. Ofin wa pe Ààrẹ gbọdọ̀ kọ lẹta sí Ààrẹ Ile-igbimo Asofin ṣaaju ki o to fi agbara le Igbakeji.
Ní àkókò yìí, Shettima wà ní Angola níbi tí ó ti ń ṣojú Nàìjíríà ní AU Extraordinary Summit, wọ́n sì n retí ipadabọ rẹ̀ ní ọsẹ̀ yìí.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
*Àṣà Tó Yàtọ̀ Sílẹ̀:
Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ láti ìgbà tí Tinubu wọlé ní May 2023 tí yóó fi lọ fún ìgbà pípẹ́ láìsí ìfipagbára fún fọọmu. Ààrẹ Muhammadu Buhari ma n fi agbara le Igbakeji rẹ̀ nigba irin-ajo pipẹ. Aṣa naa da duro lẹyin ti Igbakeji Yemi Osinbajo yọ DG SSS Lawal Daura kuro nigba ti o je Adelé Aare.
*Idi Ti O Fi Se Pataki Bayii:
Ààrẹ yóó padà lẹ́yìn “working vacation” láti darapọ̀ mọ́ ìmúrasílẹ̀ fún ìpolongo ìdìbò ti January 2027. Bayo Onanuga fi idi rẹ̀ múlẹ̀ pé Ààrẹ yóó kúrò ní Abuja lónìí, ìbùdó àkọ́kọ́ rẹ̀ ni London. Èyí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìṣèlú ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbóná fún ìdìbò gbogbogbòò tí ń bọ̀.

TINUBU BẸ̀RẸ̀ ÌSINMI Ọ̀SẸ̀ MẸ́TA NÍ EUROPE – LONDON NI IBUDO AKOKO
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti bẹ̀rẹ̀ ìsinmi ọdọọdun rẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ní Europe, ó sì kúrò ní Abuja ní Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ 30 Oṣù Kẹjọ 2026.
Komisanna ètò ìròyìn Bayo Onanuga sọ pé ìbùdó àkọ́ rẹ̀ ni London. Lẹ́yìn ìsinmi náà, yóó padà wá láti darapọ̀ mọ́ ìpolongo alágbára fún ìdìbò January 2027.
Ìbéèrè ńlá tó wà lọ́wọ́ bai ni pé: Ta ló wà lórí àleeefà? Títí di bayii, kò sí lẹ́tà fífi agbára lé Igbákejì Ààrẹ, nígbà tí Shettima fúnra rẹ̀ wà ní Angola fún ìpàdé AU.
Ẹ tẹ̀lé OJB News Yoruba fún àlàyé síwájú sí i.

3 thoughts on “TINUBU BẸ̀RẸ̀ ÌSINMI ỌLỌSẸ MẸTA L’ẸNU ISẸ SÍ ILẸ EUROPE”