Ìwádìí ọdún 1960: ṢE LÓÒÓTỌ́ NÍ PÉ AYÉ YOO PARẸ NÍNÚ OṢÙ KỌKÀNLÁ 2026

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku, 30, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

*Òpin aye 🌎 báwo tún ni kẹ̀!!!!??? 

 

Iroyin kan ń jà ránińránin lori ayelujara pe ọjọ́ kẹtàlá oṣù kọkànlá ọdún 2026 ni Òpin Ayé yóò dé, eyii ó ní í tọ́ka sí kan ju pé lẹ́yìn ọjọ kẹrìnlá oṣù kọkànlá kòní sì ibi kan tí a ó máa pè nile ayé mọ.

Se lóòótọ́ ni àbí irọ, eyii lo mú kí ikọ ìròyìn OJB News Yorùbá ṣe ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Tinubu bẹ̀rẹ̀ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ olose mẹta lọ sí ilé Europe, taani arole tí yóò máa ṣe ìjọba lẹ́yìn Tinubu?..

Kí ni òtítọ́ rẹ̀?

Alàgbà Heinz Von Foerster àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ Patricia Mora àti Lawrence Amiot ni wọ́n ṣe ìwádìí yìí ní ọdún 1960.

Àwòrán tó ń ṣe àfihàn ipare ilé ayé l’osu kọkànlá ọdún 2026

Nínú ìwé ìwádìí tí wọ́n kọ, tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ “Doomsday: Friday, 13 November, A.D. 2026”, wọ́n ṣe iṣirò mathematiki pé bí olùgbé ayé bá ń pọ̀ sí i ní iyàrá tí ó ti ń pọ̀ sí i tẹ́lẹ̀, yóó dé ibi tí yóó ti di “àìlópin” (infinity) ní ọjọ́ Etì, oṣù kọkànlá ọjọ́ kẹtàlá, ọdún 2026.

 

Àfikún Òye:

Ìwádìí yìí kì í ṣe àsọtẹ́lẹ̀ pé ayé yóó bàjẹ́ tàbí pé Ọlọ́run yóó ṣe Òpin Ayé. Iṣirò ẹ̀kọ́ mathematiki ni lásán tí ó dá lórí bí ènìyàn ṣe ń bí sí i ní àsìkò náà. Lẹ́yìn ọdún 1960, ìbísí olùgbé ayé ti fa fifalẹ̀, nítorí náà iṣirò yìí kò ṣẹlẹ̀.

OLORUN jare o! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín. Ó jẹ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀-jìnlẹ̀ àtijọ́ ni.

 

#OJBNewsYoruba #OpinAye #ImoJinle

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.