Ẹsun ikowoje #33.8 Bilionu: ILÉ ẸJỌ RÁN MINISITA AGBÁRA TẸ́LẸ̀, SALEH MAMMAH L’Ẹ̀WỌ̀N ỌDÚN MAARUNDINLOGORIN

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje, 9, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Ilé-ẹjọ́ Gíga Apapọ̀ tí ó wà nílu Abuja ti dá Mínísítà fún Agbára tẹ́lẹ̀ rí, Ogbeni Saleh Mamman, lẹ́wọ̀n ọdún 75 lẹ́yìn tí ó jẹ̀bi lórí ẹ̀sùn òní kókó mẹ́jìlá tí EFCC fi kan án, nípa ìfọ́wọ́sowọ́pọ̀ àti ṣíṣe daruke owó ará ìlú sapo rẹ, owó náà ni ó ní í ṣe pẹ̀lú owó tí a yà sọtọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ agbára omi Zungeru àti Mambilla.

 

KÍNNÍ ALÁGA EFCC SỌ? 

Alága EFCC, Ola Olukoyede, sọ nínú fídíò kan tí Arise TV pín pé ìjọba àpapọ̀ fi ₦32 billion sílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ náà, ṣùgbọ́n ₦29 billion nínú rẹ̀ ni wọ́n fì ẹ́sun kan pé Mamman yà sọ́tọ̀, tí ó sì fi ra àwọn ohun ìní fún ra’rẹ níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Sellah Mamman ni ọgbà EFCC

Ó sọ ọ́ ní Itesiwaju ọ̀rọ̀ yìí pé “Ẹnìkan lo ₦29bn tí a fẹ́ fi ṣe iṣẹ́ agbára láti ra ohun ìní tí ó wúlò fún gbogbo ìlú, ó sì rò pé kò sí ohunkóhun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn re.”

Ohun Ìyàtọ̀ Pàtàkì Tí A Gbọ́dọ̀ Mọ̀: ₦29bn Tàbí ₦33.8bn?

Nínú ìròyìn àtilẹ̀wá yìí, nọ́mbà méjì wà tí ó rọrùn láti dàpọ̀:

₦29bn lórí ₦32bn: Èyí ni nọ́mbà tí Alága EFCC sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.

₦33,804,830,503.73 (níwọ̀n ₦33.8bn): Èyí ni iye owó tí ẹ̀sùn ilé-ẹjọ́ dá lórí, tí ilé-ẹjọ́ sì rí i pé ó jẹ̀bi rẹ.

 

Nítorí náà, kò tọ́ láti sọ pé “ilé-ẹjọ́ rán an lẹ́wọ̀n nítorí ₦29bn nìkan.” Ilé-ẹjọ́ rán an lẹ́wọ̀n látàrí ẹ̀sùn ₦33.8bn náà.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Lẹ́yìn gbogbo awuyewuye lórí ikú odokunrin olórin ẹ̀mí nnì Toluwanisings, wọn yóò sìnkú rẹ nilu Ìbàdàn lónìí yìí *Lẹ́yìn idasi ileeṣẹ Ọlọpa ipinlẹ Ọyọ láti jẹ ki àlàáfíà wà láàárín ẹbi rẹ àti ìyàwó rẹ. *Bẹẹ ni àwọn èèyàn kàn sí ń béèrè fún ìwádìí òun tó ṣekú paa gan-an

Ẹgbẹ́ agbaboolu Flamingos tí de silu Abuja lónìí lati kí Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu kuule. *Ààrẹ kí wọn ká àbọ̀ pẹlu ẹ̀bùn tó jọ ju

 

Ṣé Ó Jẹ́ 85% Ní Tòótọ́?

Rárá. Tí a bá lo nọ́mbà Olukoyede fúnra rẹ̀:

₦29bn ÷ ₦32bn = 90.6% ló jẹ́, Nítorí náà, bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ 90%, kì í ṣe 85%, nínú owó tí a fi sílẹ̀ náà ni ó sọnù.

 

BÁWO NÍ WỌN ṢE DAJỌ Ẹ̀WỌ̀N ỌDÚN 75 FUN?

Ọdún 75 kì í ṣe ìdájọ́ kan ṣoṣo. Adájọ́ James Omotosho dá ẹjọ́ náà ni ipele ń pele ni, apapọ rẹ lo jẹ ọdún maarundinlogorin 75, nígbà tí adajọ dá ẹjọ́ Ọdún méje méje kọ̀ọ̀kan lọ́nà mẹwa, èyí túmọ̀ sí pé ọdún méje fún ẹ̀sùn kàn lọ́nà mẹ́wàá, lẹ́yìn náà wọn tún dá ẹ̀wọ̀n Ọdún mẹta fún ẹ̀sùn kàn, bakanna ẹ̀wọ̀n Ọdún méjì fún ẹ̀sùn kan mìíràn lọtọ, a papọ gbogbo ọdún náà jẹ ọdún maarundinlogorin.

 

Bẹẹni adajọ pàṣẹ pé kí àwọn ìjìyà náà o tẹ̀lé ara wọn (consecutively), kì í ṣe kí wọ́n lọ papọ̀ (concurrently). Nígbà tí a bá kó wọn jọ, ó di ọdún 75.

 

Ilé-ẹjọ́ kọ́kọ́ rí i pé ó jẹ̀bi ní ọjọ́ keje May 2026, ó sì dá ẹjọ́ ẹ́wọ̀n rẹ ní ọjọ́ kẹtàlá May 2026, lẹ́yìn tí ẹnì a fẹ̀sùn kan ó sì ní ilé-ẹjọ́.

Sella Mamman

KÍNNÍ PATAKI ÀWỌN IṢẸ́ NÁÀ? 

Mambilla: A bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó ní ọdún 1972. A kọ́kọ́ gbero rẹ̀ láti mú 3,050 megawatts jáde, ṣùgbọ́n wọ́n ti dín kù sí níwọ̀n 1,500MW láti jẹ́ kí ó rọrùn láti rí owó gbà. Títí di ìsinsìnyí, kò sí omi agbára kan tí ó ti ń ṣiṣẹ́ níbẹ rárá.

Zungeru: Iṣẹ́ agbára omi 700MW ní Ìpínlẹ̀ Niger, tí a ṣe láti mú agbára pọ̀ sí i fún orílẹ̀-èdè náà.

 

Èyí ni ìdí tí ẹjọ́ yìí fi ṣe pàtàkì: owó tí a fì ẹ́sun pé a yà sọ́tọ̀ jẹ́ owó tí ó yẹ kí ó ran àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́ láti rí iná mọ̀nàmọ́ná to dára jù lọ.

 

KÍNNÍ Ó TẸ̀LÉ?

Mamman ti bẹ̀bẹ̀ lọ sí Ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́millọ́rùn ní Abuja. Nínú ìwé ẹ̀bẹ̀ tí ó fi sílẹ̀ ní ọjọ́ 26 May 2026, agbẹjọ́rò rẹ̀, Femi Atteh, SAN, béèrè pé kí ilé-ẹjọ́ náà fagilé ìdájọ́ náà, kí ó sì tú u sílẹ̀. Ó sọ pé ilé-ẹjọ́ àkọ́kọ́ gbé ẹrù ẹ̀rí sórí rẹ̀, ó sì gbára lé ọ̀rọ̀ atẹnu-d’ẹnu.

 

Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti dá lejo ẹ́wọ̀n, ẹjọ́ náà kò tíì parí pátápátá títí Ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́millọ́rùn fi sọ ọ̀rọ̀ ìkẹyìn.

 

EFCC tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè fún gígba àwọn ohun ìní mìíràn tí wọ́n fì ẹ́sun pé ó jẹ mọ́ ẹjọ́ náà.

 

 

ÈRÒ TÍWÁ LÓRÍ ÌRÒYÌN YÌÍ FÚN ẸYIN ONKAWE WÁ 

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń sọ pé ìdájọ́ ọdún 75 kò tó fún irú ìwà ọ̀daràn báyìí, tí wọ́n sì ń béèrè fún ìdájọ́ líle jù. Àmọ́, ní Nàìjíríà, ìdájọ́ ikú kì í ṣe ìdájọ́ tí a sábà máa ń fi fún ẹ̀sùn fífọ owó mọ́ nìkan. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nísinsìnyí ni: Ṣé ìdájọ́ yìí yóò dúró ní Ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́millọ́rùn? Ṣé owó náà yóò padà wá? Ṣé àwọn iṣẹ́ Mambilla àti Zungeru yóò parí ní ọjọ́ kan?

Kí ni ẹ rò? Ṣé ọdún 75 tó? Ẹ sọ èrò yín nínú comment.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.