Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Esther Abike Serena, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 27, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Igbakeji Aare tẹlẹ, Alhaji Atiku Abubakar ti korin fun Ijoba Apapo pe ki wọn ṣe iwadii rẹ ti wọn ba ni ẹri ti o so oun pọ mọ owo $16 bilionu dola ti a sọ pe ijoba lo lori ina nigba ti oun wa ni ijoba.
KINI O ṢẸLẸ:
Oro owo $16bn ina yii ti wa lati igba ijoba Olusegun Obasanjo (1999-2007) ti Atiku je Igbakeji Aare. Awon kan so pe owo naa lo laisi ina kankan.
Buhari ni 2018 ti beere: “Nibo ni ina ti $16bn naa wa?”
Obasanjo dahun: “Mo ti ṣetan fun iwadii, ẹ lọ ka iwe mi My Watch Chapter 41-47, EFCC ati National Assembly ti fọ mi mọ tẹlẹ”
APC ni igba kan ti pe Obasanjo ati Atiku ki wọn ṣe alaye owo naa tabi ki wọn dakẹ
Atiku ni: “Sowore ko mọ nkankan, ẹ lọ ṣalaye idi ti ina ko fi wa”

Bayi, lẹyin ti Atiku tun korin fun Tinubu lori N17.5 trillion ti NNPC lo lori aabo paipu epo ni osu 12 nikan, o tun n korin fun Ijoba Apapo:
“Ti ẹ ba ni ẹri pe mo je ninu $16bn ina, ẹ mu mi lọ sile-ẹjọ, ẹ ṣe iwadii mi.”
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ni Mowe Ibafo, ọwọ ọlọpaa tẹ àwọn ènìyàn tó ní fi ọmọ ṣe okoowo nínú ilé akoku…
Idi ti oro yii fi tun n jade ni bayi:
Atiku fe fi han pe oun ko beru iwadii, oun n beere akoyawo
O fe fi oju han pe Ijoba Tinubu ti o n na N17.5tn ni o yẹ ki a ṣe iwadii, kii ṣe oun
Iwe-aṣẹ Obasanjo ati EFCC ti fọ Obasanjo mọ tẹlẹ, sugbon awọn ara Naijiria ko gbagbọ
Ina Naijiria si tun wa ni ipo buruku lẹyin $16bn + $5.3bn Yar’Adua + $8.2bn Jonathan
Kini O Yẹ Ki Ijoba Ṣe?
Gẹgẹ bi SERAP ati ACF ti beere, Ijoba gbọdọ:
Fi gbogbo iwe-aṣẹ $16bn naa han
Pe Obasanjo, Atiku, ati awọn ti o kan si EFCC ti o ba ni ẹri
Ma fi oro yii ṣe ere oselu
OJB NEWS YORÙBÁ | POLITICS | 26-08-2026
