OLUBADAN KILỌ FUN AWỌN OBINRIN, Ẹ MÁA ṢE JÁDE LỌJỌ AJÉ ỌSẸ TO N BỌ

*Eegun Olóòlù yóò jade ní Ìbàdàn, obìnrin kò gbọdọ̀ fi ojú kan an – Oba Ladoja

Orísun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Àìkú, 26, Oṣù Keje 2026 

 

Olubadan ilu Ibadan, Oba Rasidi Adewolu Ladoja (Arusa I), ti kilọ fun gbogbo awọn obinrin ni ilu Ibadan ati agbegbe rẹ lati ṣọra gidigidi ni ọjọ Ajé ọsẹ ti n bọ.

 

Kabiesi, ninu ikilọ rẹ, sọ pe Eegun Olóòlù, eegun ibilẹ pataki ni ilu Ibadan, yoo jade laiyara ọjọ naa, nitori naa ko yẹ ki obinrin kankan fi oju kan an.

 

Gẹgẹ bi ọrọ Olubadan:

“Ẹyin obinrin, ẹ ṣọra yin lati ọjọ Ajé ti i ṣe Monday ọsẹ to n bọ. Eegun Olóòlù yoo jade ni Ibadan, obinrin ko si gbọdọ fi oju kan an rara.”

Oba Ladoja tẹnumọ pe ofin ibilẹ yii wa lati ọjọ pipẹ, ati pe o yẹ ki awọn obinrin tẹle e fun alaafia ati bọwọ fun aṣa ilu Ibadan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.