*Ko sẹni to ní ètò abayọ kankan si isoro Naijiria ninu awọn to fẹ́ gba ijọba lọ́wọ́ rẹ̀ – Gomina Eko tẹlẹ̀
Orísun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 23, Oṣù Keje 2026
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ati Minisita agba, Ogbeni Babatunde Raji Fashola (SAN), ti kede atilẹyin rẹ fun saa keji Aarẹ Bola Ahmed Tinubu.
Fashola sọ eyi di mimọ ninu ọrọ kan to sọ laipẹ yii, nibiti o ti ni, o yẹ ki awọn ọmọ Naijiria gba Aarẹ Tinubu laaye lati pari saa odun mẹjọ rẹ.
GẸ́GẸ́ BÍ ỌRỌ RẸ :
“Ẹ wo o, o maa dara ki ẹ jẹ ki Tinubu pari saa ọdun mẹjọ rẹ. Mo ti wo gbogbo awọn alatako ti wọn lọwọlọwọ ti wọn fẹ gba ijọba lọwọ rẹ, emi ko ri ẹni kankan ninu wọn ti o sọ ọna abayọ si isoro Naijiria tabi ti o sọ ohun ti yoo ṣe ti o yatọ si ohun ti Tinubu n ṣe lọwọlọwọ.”
Amofin agba naa tẹnumọ pe ko si ero pataki tabi eto idagbasoke ti o yatọ ti awọn alatako n ṣafihan ju ohun ti ijọba alade lọwọlọwọ n ṣe lọ.
