LÁTI ILEEṢẸ OLUSIRO OWO ÀGBÀ LO P’ASẸ FÚN WÁ LÁTI SÍ APO IFOWOPAMOSI FUN PFIPC – CBN

Banki àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN, ti jáwọ́ nínú ọ̀rọ̀ ariyanjiyan ajọ Presidential Foreign Intervention Promotion Council, PFIPC, níwájú igbìmọ̀ iwadii ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣofin ní Abuja.

 

Gẹ́gẹ́ bí alága àgbà kan láti CBN, Ọ̀gbẹ́ni Hamisu Abdullahi, ṣe ṣàlàyé níwájú igbìmọ̀ náà, òun sọ wípé kìí ṣe ìpinnu CBN fúnra rẹ̀ ni ṣíṣí àkántì méjì fún ajọ PFIPC, bí kò ṣe pé àṣẹ ni wọ́n gba láti ọ́fíìsì Olùṣirò Owó Àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

 

KÍ NÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ ?

 

Ọ̀rọ̀ ajọ PFIPC ti di ariwo ńlá lẹ́yìn tí ẹ̀sùn àìṣedéédéé kan jáde síta.

 

Ọgbẹni Adeniyi, ẹni tí wọ́n sọ pé òun ni adarí ajọ PFIPC, ti fi ẹsùn kan Adarí àwọn òṣìṣẹ́ nílé iṣẹ́ Ààrẹ, Rt. Hon. Femi Gbajabiamila, pé òun ni ó dá ajọ náà sílẹ̀ fún ìwà jẹgúdú jẹra.

 

ADENIYI SỌ PÉ :

 

Òní òun san N400m fún Gbajabiamila láti gba ipò gẹ́gẹ́ bí olórí àgbà ajọ PFIPC, àti pé ó gba owó náà nípasẹ̀ olóògbé Babatunde Dolapo Tanimola.

Gbajabiamila tún béèrè fún ìdá 48% nínú N27.3bn tí ajọ náà yóò fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

 

Ṣùgbọ́n Gbajabiamila ti kọ gbogbo ẹ̀sùn náà pátápátá, ó ní irọ́ pàtá ni Adeniyi ń pa. Nítorí èyí, Gbaja ti gbé Adeniyi lọ sí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìbanilọ́rúkọjẹ, níbi tí ó ti ń béèrè fún N15bn gẹ́gẹ́ bí owó ìbàwí.

 

Ìwádìí síwájú sì fihàn pé Adeniyi náà fúnra rẹ̀ gba àṣẹ láti ní ọ́fíìsì nílé iṣẹ́ ìjọba ní Abuja àti láti lọ ṣí àkántì méjì pẹ̀lú CBN.

 

KÍ NÍ CBN SỌ NÍWÁJÚ ILÉ AṢÒFIN ?

 

Nígbà tí wọ́n pè CBN láti wá ṣàlàyé, Ọ̀gbẹ́ni Hamisu Abdullahi tí ó dúró fún CBN sọ báyìí:

“Ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Keje ọdún 2025 ni CBN ṣí àkántì méjèèjì fún ajọ PFIPC. Àkántì àkọ́kọ́ jẹ́ ti owó Dọ́là, èkejì sì jẹ́ ti owó Pọ́ùn Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àṣẹ láti ọ́fíìsì Olùṣirò Owó Àgbà ni a tẹ̀lé láti ṣí wọn.”

Ó tẹ̀síwájú pé bí wọ́n tilẹ̀ ṣí àkántì méjèèjì náà, àkántì náà kò ṣiṣẹ́ rárá. Ìdí ni pé ajọ PFIPC kùnà láti pèsè àwọn ènìyàn tí yóò máa ṣe ìbuwọ́lu fún àkántì náà, tí wọ́n ń pè ní Signatories.

 

Ní báyìí, ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣofin sọ pé ìwádìí wọn yóò tẹ̀síwájú, nígbà tí ẹjọ́ tí Gbajabiamila fi kan Adeniyi ní ilé ẹjọ́ náà tún ń lọ lọ́wọ́.

 

OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ yìí kí a sì máa fún yín ní ìròyìn tuntun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.