Ariwo ńlá tí gbà ori ẹrọ ayelujara lẹhin ti gbajugbaja alawada orí TikTok, Habeeb Adelaja ti gbogbo eniyan mọ si Peller, ti sọ iye owo aso ebi igbeyawo rẹ ati ayaba rẹ, Jarvis (Elizabeth Aminata) síta fún àwọn olólùfẹ́ rẹ
Ninu ifọrọwerọ lori TikTok Live rẹ pẹlu 10 Naira, Peller sọ pe:
1. Owo Aso Ebi naa ga ju: Aso ebi yadi mẹjọ (8 yards) ni N700,000, ti ẹni ba si fẹ ọ̀pá mejila (12 yards) yoo san N1,000,000.
2. Alejo diẹ nikan: O sọ pe awọn alejo tí ìyè wọn pe jẹ irínwó 400 nìkan, ati pe aso naa ti fẹrẹẹ ta tán nilẹ.
3. Ofin Igbeyawo naa le: Peller kilọ pe ẹnikẹni ti ko ba wọ aso ebi osise tabi ti ko ni iwe ifiwepe, wọn o ni jẹ ki o wọle si ibi ayẹyẹ naa.
Iroyin yii ti mu ariwo wá níta nitori pe Peller ti san owo ori iyawo Jarvis tẹlẹ ni ipinlẹ Edo, ati pe igbeyawo funfun wọn ti a gbọ pe yoo waye ni August 1, 2026 ti n sunmọ.
Nigba ti Peller n ṣalaye fun 10 Naira to fẹ ra fun eniyan mẹrin, o ṣe isiro pe iye owo naa yoo jẹ N1.4 million.
Ọpọlọpọ awọn ololufẹ wọn lori ayelujara ti pin si meji, awọn kan sọ pe o yẹ fun iru igbeyawo nla bẹẹ, awọn miran si sọ pe owo naa ti pọ ju.
Kí ni èrò rẹ? Ṣé o le ra Aso Ebi N700k fun igbeyawo Peller àti Jarvis? Fi èrò rẹ sọwọ sì abala ariwisi comment section
A óò tẹ̀síwájú láti tẹ̀lé ìtàn yìí. Bí ẹ bá ní ìròyìn tó wúlò, ẹ kàn sí wa ní newsroom@ojbmedias.com.ng tàbí kí ẹ pè 0806 695 2410 +2348076452810
