MUHAMMAD MA’AJI SỌPE MI Ò KABAMO PÉ MO FẸ DÍTẸ̀ GBA IJỌBA LỌWỌ TINUBU

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 6, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Nàìjíríà fẹrẹ wọlẹ, mo ṣe ohun tí mo ṣe nitori ifẹ orilẹ-ede – Kọ́lọ́nẹ́lì Mohammed Ma’aji ti wọn fẹsun kan lé lori iditẹ lọwọ Tinubu sọ. O ni Nàìjíríà ti fẹrẹ bajẹ patapata nitori iṣoro ọrọ aje.

 

ÌRÒYÌN KIKUN:

 

Wahala nla ti tu si orilẹ-ede Nàìjíríà bi Kọ́lọ́nẹ́lì Mohammed Ma’aji (N/10668), ọmọ bibi Edati, Niger State, ọmọ 47 Regular Course, ti wọn pe ni olori igbiyanju iditẹ lọwọ ijọba Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe ohun ti o ṣe, o ṣe fun orilẹ-ede.

 

Gẹgẹ bi iwadii Premium Times ati AllAfrica ṣe sọ:

• Ni September 2025, awọn alaṣẹ ologun bẹrẹ si mu awọn oṣiṣẹ ologun ti wọn fura si, pẹlu Ma’aji. Ni October 2025, awọn oṣiṣẹ ologun 16 ti wọn ti mu danu. • Ni akọkọ, ologun sọ pe wọn n ṣe iwadii “ìwà àìbọ̀wọ̀”, ṣugbọn lẹhin oṣu meji, wọn jẹwọ pe iditẹ lo jẹ. • Ma’aji jẹ olori 19 Battalion ni Okitipupa, Ondo State, o ti ṣiṣẹ ni Niger Delta, o si kopa ninu Operation Crocodile Smile II ni 2017. • Wọn gbagbọ pe oun ni asáájú ati olowo fun iditẹ naa – oun ni o n gbe owo fun awọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Ero Ma’aji:

 

Ma’aji sọ fun awọn oluwadii pe Nàìjíríà fẹrẹ wọlẹ nitori iṣoro ọrọ aje, ebi n pa eniyan, owo orilẹ-ede ti ṣubu. O ni ohun ti o ṣe jẹ ti ifẹ orilẹ-ede, kii ṣe ti ara ẹni.

 

Ṣugbọn Minisita Aabo tẹlẹ, General Christopher Musa, sọ pe Ma’aji n ṣe bẹẹ nitori wọn kọ lati gbe e ga di Brigadier General. O ni “o ko ni mark to lati gbe ga”.

 

OHUN TÍ WỌN FẸ ṢE :

 

Awọn oluwadii sọ pe awọn oludiditẹ fẹ pa Tinubu, Kashim Shettima, Godswill Akpabio, ati Tajudeen Abbas, wọn si ti kọ iwe nipa bi wọn yoo ṣe yi eto oselu pada.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

Àwọn olókìkí ìfẹ́ ìgbàanì bí olóògbé Olasoji, Sunmola Osunmuukomi

KÍNNÍ Ó ṢẸLẸ BÁYÌÍ ?

• Tinubu ti yọ gbogbo Service Chiefs kuro, o pe Olufemi Oluyede di Chief of Defence Staff

 

• Lẹhin wahala, o pe Christopher Musa pada di Minisita Aabo. • Ẹjọ naa wa niwaju Justice Joyce Abdulmalik ni Abuja lori ẹsun 13 – treason, conspiracy to wage war.

Ma’aji wa ni atimọle, wọn sọ pe ko ronupiwada rara, ko si n fọwọsowọpọ.

 

OJB News Yorùbá yoo ma tẹle ẹjọ naa.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.