Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje 10, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Pa Olasoji Sunmola Osunmukomi, ti gbogbo eniyan mo si SOJI-OPA ni odun 1960, ni won bi ni odun 1908 ni Agbo-Ile Opa, agbegbe Igbodo, ni Ile-Ife. Baba re ni Pa Osunmukomi, iya re si ni Mama Ooresola Osunmukomi lati Ile-Ijato ni Ile-Ife. Iya re di Iya Ijo ni Ijo Salvation Army, Ajamopo, Ile-Ife.
Ni akoko, Pa Soji-Opa se ise agbe ni Iloro, leyin naa o ko ise awakọ lodo Pa Seedu, eni ti o je awakọ akọkọ ti ijoba fun ni iwe-ase ni agbegbe Ife ni odun 1950.
Kristeni ni won bi Soji-Opa, o si n sin ni Ijo Salvation Army, Ajamopo. Sugbon nigba ti o bere lati ko awakọ lodo Pa Seedu, o di Musulumi, won si so orukọ re ni Ismaeel Sunmola. O dara pupọ ninu ise awakọ, oriire si yọ si i, o di olowo ọkọ nla ni agbegbe Ife, o si di eniyan olokiki ni Ife ati Ijesha. Ni akoko ola nla re, o ni ọpọlọpọ awọn ọkọ nla (truck) ti orisiirisii.
Pa Sunmola Soji-Opa gbe ise re lọ siwaju, o bẹrẹ si ra ọja oko-owo, iṣẹ ti o wulo julọ ni odun 1960 ati 1970. Aseyori re ninu ọkọ lo fun ni anfaani lati bẹrẹ si gbe koko jade lọ si oke-okun, o si ni ọgọrọ awọn oṣiṣẹ.
Eniyan oninurere ati oninuure ni. O je ọkan ninu awọn agba olokiki ti ilu Ife. Awọn ọrẹ rẹ to sunmọ ni Pa Disu Ire Akari, Pa Agbeti, Pa Lawal Oba-bi-Olorun-Kosi, Pa Adewoyin, ati Pa Owojori Omisore, ti o je ebi re ni Agbo-Ile Opa. Ni asiko naa, awọn eniyan wọnyi ni wọn n dari ilu Ife ati agbegbe re, gbogbo wọn si jẹ akikanju ninu iṣẹ wọn.
Ọkan ninu awọn ohun pataki ninu aye re ni pe nitori iriri nla re ninu iṣowo koko, ijọba Iwọ-Oorun Yan an gẹgẹ bi ọmọ Igbimọ Cocoa Board ni Ibadan, olu-ilu Iwọ-Oorun Nigeria ni igba naa.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
Pa Osunmukomi tun je onisowo nla, o bẹrẹ si ta epo pẹlu ile-iṣẹ Esso, o si ni ibudo epo tirẹ ni Lagere, Ile-Ife.
Pa Sunmola Soji-Opa ni ọpọlọpọ aya, o si je oloro ati olowo. Bi o tilẹ je pe olokiki ni, o mọ bi a ṣe n ṣakoso owo, eniyan ati dukia. Nigba ti o ku ni ọjọ kejilelogun (22) Oṣu Kẹwa ọdun 1974, o fi ọpọlọpọ ọmọ rere ti o fun ni ẹkọ silẹ, lara wọn ni Dokita Gani Olasoji, olukọni nla, ati awọn miiran.
Apakan itan naa ni pe iku re mì gbogbo ilu Ife, nitori kii ṣe olowo ọkọ nikan ni, oluranlọwọ nla fun ọpọlọpọ ara Ife ni.
Loni, bi o tilẹ ti ku, o fi ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ-ọmọ silẹ, lara wọn ni Ooni Ife lọwọlọwọ, Oba Adeyeye Babatunde Enitan Ogunwusi, Ojaja II, nipasẹ ọkọ ọmọbinrin rẹ akọbi, Prince Aderopo Ogunwusi ti Agbo-Ile Ojaja (Idile Giesi), ati aya re Mrs Sidikatu Wuraola Abegbe Ogunwusi, ti a bi ni Soji-Opa.
Ki ọkàn Pa Soji-Opa, akọni Ife, sun ni alaafia pipe.
Ao tún mú ìtàn akọni mìíràn wà fún yín laipẹ
