Orísun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Akindele Oluwaseun, Ilorin | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 28, Oṣù Keje 2026.
Ìpayà àti ariwo ló ṣe ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn nípa ẹjọ́ tó wà láàrín akọrin ìbílẹ̀, Bennylee Ifagbemiro Olamigoke Adewola àti àwọn ẹgbẹ́ kan ní Ilorin tí wọ́n ń jẹ́ Ilorin Muslim Heritage àti Ilorin Heritage Preservation Foundation (Ogo Ilorin).
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ẹ̀sùn ọ̀daràn tààrà tí ó jẹ́ June 19, 2026 tí ó wà ní Kóòtù Majisreeti Ilorin ṣe fi hàn, àwọn olùfìsùn náà sọ pé Bennylee fi ìkòkò amọ̀ tí ó ní ẹyin sísè àti epo pupa sí orí Qur’ani Mimọ́, ó sì gbé fọ́tò àti fídíò rẹ̀ sórí ẹ̀rọ ayélujára (X, Facebook, TikTok, YouTube).
Wọ́n tún fi ẹ̀sùn kàn án pé ó kọ ọ̀rọ̀ yìí:
“AL QUR’AN HAS BEEN DISGRACED IN YORUBA LAND… ISLAM RELIGION HAS BECOME A USELESS RELIGION”
NÍTORÍ ÈYÍ, WỌ́N FI Ẹ̀SÙN MẸ́RIN KÀN ÁN :
*Pípa rògbòdìyàn àti ìdàrú sókè ní ìlú
*Ẹ̀gàn sí ẹ̀sìn àti ìbàjẹ́ sí ìgbàgbọ́
*Ìbàjẹ́ sí ibi mímọ́
*Pípa ìtàn èké tó lè ba àlàáfíà jẹ́
KÍ NI KÓÒTÙ ṢÉ ?
Kóòtù pa àṣẹ pé kí wọ́n pè Bennylee wá ní July 25, 2026 nípa ìpolówó orí ìwé ìròyìn àti láti inú ẹ̀rọ ayélujára. Bennylee kò farahàn ní Kóòtù ní ọjọ́ náà.
Ní ọjọ́ July 28, 2026, Bennylee fúnra rẹ̀ fi ẹ̀gàn kọ orí Facebook rẹ̀ pé: “Ṣé ẹ fẹ́ yá owó ní Kóòtù láti wá mú mi ni?”
Lẹ́yìn tí agbẹjọ́rò àwọn olùfìsùn gbé ọ̀rọ̀ sókè, Aláṣẹ Kóòtù sun ẹjọ́ náà síwájú sí Ọjọ́bọ, August 6, 2026, kí Bennylee lè wá dáhùn sí àwọn ẹ̀sùn náà.
ẸJỌ́ KEJÌ TÓ SÌ WÀ
Èyí kọ́ ni ẹjọ́ àkọ́kọ́. Bennylee fúnra rẹ̀ tún ń bá àwọn kan jà lórí ilé Iya Ilorin (Iya Abiye / Iyalorisa) tí àwọn ènìyàn kan jóná ní Ilorin. Nínú ẹjọ́ yẹn, òun ni olùfìsùn, wọ́n sì ti sun ẹjọ́ náà sí May 18, 2026 ní High Court Ilorin.
Títí di àsìkò yìí, kò sí ẹnikẹ́ni tí Kóòtù ti dá lẹ́bi, Kóòtù nìkan ni ó ń gbìyànjú láti rí i dájú pé gbogbo ẹgbẹ́ wá síwájú rẹ̀ láti jẹ́jọ́.
TANI BENNYLEE ?
Bennylee jẹ́ ọmọ bibi Ondo State, akọrin Oba, akọrin ìbílẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ fún orin rẹ̀ “Imo Lile” àti bí ó ṣe ń dẹ́fẹ́ndì ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá (Isese). Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olólùfẹ́ lórí TikTok tí wọ́n ń pè é ní Ẹlẹ́bọ AjagbemoMuslim.
