Orísun: OJB News Yorùbá | Onkotan: Olalekan Akanji Ademeto | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun: 28, Oṣù Keje 2026.
Moki gbogbo eyin ayanfe wa kaari aye nibi gbogbo ti e ti n gbo oro mi lojo toni, Olalekan Akanji iko Ademeto omo Baba ni Ijeru ogbomoso loruko temi, lori eto Laye Igbaani,nibi tawon akoni igbaani fi a dagba eto rosi, itan Jesu Oyinbo laso tan laipe yi, sugbon loni ode yi, ti gbajumo ati akoni omo yoruba nni, Duro Ladiipo la o mu wa o, ni ipinle Oyo ijohun, ilu kan wa ti won n pe ni ilu Oshogbo, ilu Oshogbo ti wa labe ipinle Osun bai, ilu Oshogbo yi gan-an ni won ti bi Duro Ladiipo, and o yaa e je kama gbadun itan na bai.
Ni awujọ awọn osere tiata, odu ni oloogbe Duro Ladipọ, kii si se aimọ fun oloko. Bi onirese Duro Ladipọ ko si fingba mọ, eyi to ti fin silẹ ko to jade laye ko lee parun, tori pe o dabira lagbo tiata ko to jade laye.
Se bo se gbe isẹ tiata lọ soke okun ni ka sọ ni abi aimọye ere itage akọnilọgbọn to ti gbe se nigba to wa loke eepẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe Duro Ladipọ ko si laye mọ, ọpọ awọn agba iwoyi ni ko lee gbagbe ere Ọba Koso, Sango, Ajagun Nla, Ẹda, Bode Wasinmi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Gẹgẹ ba se gbo nipa akoni, agba oje nifi ise ere ori itage nni, gege bi mo se so fun yin ri pe itan manigbagbe gbaa ni itan igbe aye oloogbe Duro Ladipọ, eyi to yẹ kawọn ode iwoyi fi se awokọse ati arikọgbọn gidi.
Eyi ni ohun to yẹ ko mọ nipa Oloogbe Duro Ladipọ ati bose lo igbesi aye re :
Ọjọ Kejidinlogun osu Kejila ọdun 1931 ni Duro Ladipọ de ile aye, ti wọn si bi si ilu Osogbo, se odo kii san, ko ma ni orirun
Ọmọlẹyin Kristi gidi, to wa lati idile onigbagbọ ni Duro Ladipọ, ti baba rẹ si jẹ ojisẹ Ọlọrun lati inu ijọ Angilika amọ baba baba rẹ to wa lati ilu Ọyọ ijọun, jẹ Onisango ati Ọlọya
Niwọn igba to jẹ pe ẹjẹ ni agbara, bi o tilẹ jẹ pe inu ẹsin igbagbọ ni wọn bi Duro si, sibẹ, o nifẹ si awọn ohun asa isẹnbaye gẹgẹ bi baba rẹ agba ti n se. Nigba to wa ni ọmọde, o maa n yọ kelekele kuro ni ile alufa to wa ninu ọgba sọọsi, lati lọ wo iran egungun ati awọn ajọdun orisa miran ti wọn n se nigba naa
Duro Ladipọ lo koko bẹrẹ lilo awọn ilu isẹnbaye ninu ijọ ọmọlẹyin Kristi, nigba ti awon agbaagba ijo wo pe eleyi fe pa ilana ijo Olorun pada ni won ba le kuro ninu ijọ beeni awon kan feran awon ilu isembaye ti Duro muwo ijo Olorun yi, bee loje pe lati akoko naa, asa yii ko parun titi doni, ti wọn si n lo ilu abalaye lasiko ọdun Keresi ati ninu ile ijosin kiri ile yi, . Duro Ladipọ si gba ami ẹyẹ latọwọ aarẹ Naijiria nigba naa, Ọmọwe Nnamdi Azikwe lasiko ọdun keresi kan to waye ni ibudo iko nkan isẹnbaye lọjọ si to wa ni Onikan, nilu Eko
Ifẹ to ni si asa isẹmbaye yii si lo tii titi de idi tiata, ti ọpọ ere rẹ naa si maa n se agbelarugẹ awọn ohun ajogunba wa nilẹ Kaarọ oojire, nibi yi la o gbe da enu duro loni lori itan akoni elere ori itage nni, Oloogbe Duro Ladiipo, titi ojo min-in ojo Ire, emi ni maa ma wa, eyin ni maa ma ba lase Edumaree, agbe mi se tan, o n r’ode idaro, Aluko mi se tan, o n rode ikosun, Lekenleke mi se tan o n r’ode ikefun nini-n-nini, Emi Olalekan Akanji iko Ademeto omo Baba ni Ijeru ogbomoso mo n re ile Baba tobi mi lomo, Oodua a gbeyin o, yoo gbe iran mi lase Edumaree, Ire oo
Lẹyin ti Duro Ladipọ ka iwe tan nilu Osogbo, lo wa si Ibadan, lati se isẹ Olukọ lọdun 1960, to si ti idi isẹ olukọ dara pọ mọ ẹgbẹ osere tiata Mbari Mbayọ pẹlu iranlọwọ oyinbo alawọ funfun kan lati orilẹede Germany, Ulli Beier, ẹni to nifẹ si awọn ohun isẹnbaye. Amọ ko pẹ lẹyin naa, to fi pada silu Osogbo, to si da ẹgbẹ osere tiẹ silẹ lọdun 1961
Duro Ladipọ ni ẹbun orin kikọ ati ilu lilu, eyi to maa n se afihan wọn ninu ere rẹ, to fi mọ amulo owe pipa. Lara awọn ere tiata to si jẹ ki Duro Ladipọ di ilumọọka ni Ọba Moro eyi to se lọdun 1962, Ọba Koso ati Ọba Waja, ti wọn jade lọdun 1964, Mọremi, Suuru baba Iwa, Tanimowo Iku, Bode Wasinmi, Ajagun nla ati bẹẹ bẹẹ lọ
Duro Ladipọ lọ si ọpọ orilẹede jakejado agbaye lati se afihan ere ori itage rẹ. Lara awọn orilẹede ti Duro Ladipọ atawọn ọmọ ẹgbẹ osere rẹ lọ ni Amẹrika, Holland, France, Italy, Yugoslavia¸Iran, Belgium, Scotland, Swizerland ati bẹẹ bẹẹ lọ
Ọpọ ami ẹyẹ ni Duro Ladipọ gba ninu ere tiata lorilẹ ede Naijiria ati loke okun. Lara rẹ ni eyi to gba ni orilẹede Germany nibi ajọdun isẹ ọnati ilu Berlin lọdun 1964 ati ami ẹyẹ to gba ni ajọdun isẹ ọna Commonwealth lọdun 1965
Ere tiata mẹrindinlogoji ni Duro Ladipọ kọ, to si se jade, nigba to kọ ere mẹwa, to si ko awo ere mẹsan sita lori ẹrọ giramofonu, to si se ere fiimu mẹrin
Lara awọn osere tiata ti wọn jẹ akẹẹgbẹ Duro Ladipọ ni Kọla Ogunmọla, Ọla Rotimi, Herbert Ogunde, Ayox Arisekọla, Ojo Ladipọ, Moses Ọlaiya Adejumọ ( Baba Sala), Oyin Adejọbi, Isọla Ogunsọla ( I show pepper) ati bẹẹ bẹẹ lọ
Duro Ladipọ ni ọpọ iyawo, to si tun bi ọmọ pupọ, amọ eyi to jẹ aayo ninu awọn iyawo rẹ ti gbogbo aye mọ ni Mama Abiọdun Duro Ladipọ, to maa n se ere Ọya, nigba ti Duro ba se Sango
Ọjọ nla ni ọjọ Kọkanla, osu Kẹta ọdun 1978 ti Duro Ladipọ mi kanlẹ, to si ki aye pe o digbose
Gẹgẹ bii orisa Sango ti gbogbo eeyan mọ si, apẹẹrẹ Sango lo jẹyọ lọjọ ti Duro Ladipọ jade laye, nitori ojo nla, to mu ara lọwọ lo rọ lọjọ naa, ti ara si n sana gidigidi. Asiko ojo ati ara nla yii na si ni Duro Ladipọ mi kanlẹ, ti akukọ si kọ lẹyin ọmọkunrin rẹ.
Duro Ladipọ̀ ti wa sile aye, to si ti lọ amọ̀ ko kọ̀ja nile aye gẹgẹ bii ejo to kọja lori apata, ti ko ni ipa kankan.
Kii kuku se pe Duro Ladipọ ka iwe rẹpẹtẹ ko to se aseyọri, amọ o lo ẹbun atinuda ti Ọlọrun fun lati ta ara rẹ yọ, to si di ilumọọka lawujọ agbanla aye.
Ki ni awọn talẹnti ti iwọ naa ro pe o ni? bawo lo si se lee lo talẹnti naa fun agbega iran rẹ, ti orukọ rẹ ko si ni di igbagbe?
Eyi lo yẹ ko jẹ ibeere ti yoo jẹ wa logun, ka si lọ se awari talẹnti wa gẹgẹ bi Duro Ladipọ ti se, kawa naa le wọ inu iwe itan manigbagbe.
