ÈYÍ I NI ÌTÀN ỌMỌ ÌLÚ IFẸ̀ TO ṢE IGBAKEJI GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ NÍGBÀ KAN, OLOYE RAFIU ADEYEFA JAFOJO

Orísun: OJB News Yoruba | Onkotan: Lekan Lawal, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 12, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Chief Rafiu Bakare Adeyefa Jafojo ni a bi ni December 6, 1936. Baba rẹ ni Late Bakare Adeyefa Jafojo, ọmọ ile Orunto, Iremo Quarters, Ile-Ife. Baba-baba rẹ jade kuro ni Ile-Ife ni ọdun 100 sẹhin nitori wọn ko fun un ni ẹtu lati jẹ Obalufe.

O lọ si Awori – Ikeja ati Agege. Nibẹ ni baba rẹ ti fẹ iya rẹ, Madam Taiwo Jafojo (Nee Adebunmi) lati Isale Awori, Ikeja. Nitori naa ni Rafiu fi dagba si Ikeja lọdọ awọn Awori, iya rẹ.

 

O bẹrẹ ile-iwe alakoobere ni Alafia Institute, Ibadan, o si pari WASC ni Christ High School, Ilubirin, Lagos. O ṣiṣẹ bi Building Inspector ni Ikeja Local Government (1959-1960).

Ni 1961, o lọ si UK – Hackney Technical College (1964-66), Brixton College of Building (1967-69), ati Northern Polytechnic, Holloway (1969-70) nibiti o ti gba Advanced Certificate in Building Technology.

Nigba ti o wa ni UK, o darapọ mọ West African Students Union ati Egbe Afenifere UK. Nigba ti o pada ni 1970, Awori Welfare Association (AWAN) pe e sinu ija fun ominira Awori.

O bori bi Councilor ni Ikeja Local Government (1975-1977) ati Chairman, General Purpose Committee.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

Ikú tí wó agbolé àwọn osere, agboolé àwọn olorin ìgbàgbọ́ ló gbà lọ, tí ó pá Alàgbà…..

Àwọn kàn tí wá ti wọn ti lànà ìgbádùn tí a ń lò lásìkò yíì, lára wọn ni Olóògbé Olasoji Sunmola Osunmuukomi nilu ilé-ìfẹ́

 

Ni 1978, o jẹ ọkan ninu awọn oludasilẹ Unity Party of Nigeria (UPN) ti Chief Obafemi Awolowo. Awolowo yan an bi Deputy si Lateef Jakande nitori agbara ibo Awori.

Wọn bori ni 1979 bi Gomina akọkọ ati Igbakeji Gomina akọkọ ti Lagos State, wọn tun bori ni 1983 titi di coup December 1983. Ijọba wọn ni wọn ka si ijọba to dara julo – wọn kọ LASU, LTV/Radio, Alausa Secretariat, ile-iwe ọfẹ, ilera ọfẹ, ati awọn ile olowo poku.

 

Wọn fi awọn oye si i: Olota of Ikejaland, Eesorun of Orile-Agege, Asiwaju of Isolo.

Lẹhin ipo, o ṣi jẹ oloselu nla, o sunmọ Ooni Okunade Sijuwade, o si ran lọwọ lati fun Obalufe ni ade.

O ku ni 2016, iyawo rẹ ni Madam Mosunmola Jafojo (ti wọn fẹ ni 1962 ni UK), ọpọlọpọ awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ tó gbé yín rẹ.

Oríkì rẹ: “Rafiu Omo Jaojo, Omo Adeyefa, Omo Orunto Obalufe, Omo Ooni-ode…”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.