Orisun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Èkó |Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 30, Oṣu Keje 2026
Ẹgbẹ́ to n polongo àti tita àwọn àwo onkorin lórílẹ̀ èdè yìí Music Advertisement Association of Nigeria MAAN tí fi àmì ẹyẹ oṣiṣẹ tí ó peregede julọ lẹ́nu iṣẹ ọba fún 2025 dá ọga àgbà ní ilééṣẹ́ to n ri si idaabo bo àwùjọ àti imo tótó àyíká Lagos state everomental protection LASEPA
Arábìnrin Olabisi Shonibare lọla ni Alahusa lọsan àná ọjọ ọjọru, ṣáájú kí Ààrẹ ẹgbẹ́ MAAN Dókítà Surajudeen Adewale Amusat Hazraj ló ti kọkọ́ sọ̀rọ̀ nípa ifomoniyan àti ìfaradà lẹ́nu iṣẹ ọba tí Arabinrin Shonibare ni, bẹẹni Ààrẹ Amusat kò sai gbóríyìn fún ileeṣẹ LASEPA fún bí wọn ṣe ń dáàbò bo àwùjọ àti àwọn èèyàn ìlú Èkó lọ́wọ́ àwọn ẹ̀gbin àyíká àti ewu inú afẹ́fẹ́.
Ọ̀gá àgbà LASEPA Arabinrin Olabisi Shonibare kò sai dúpẹ́ pupọ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ MAAN àti àwọn olórí ẹgbẹ́ náà fún ẹ̀mí iṣọkan tí wọn fi ń túkọ̀ ẹgbẹ́ náà pẹlu bí wọn ṣe ń fowosowopo pẹlu ileeṣẹ LASEPA fún igbega àti ilọsiwaju ìlú Èkó lapapọ.
Nínú àwọn tí ó wà níbi ayẹyẹ náà ni Àwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ LASEPA Gómìnà ẹgbẹ́ MAAN ni ipinlẹ Èkó, Mercyland music, Ọgbẹni John Babalola Jobab music, àti bẹẹbẹẹ lọ
