Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 29, Oṣù Keje 2026.
Wàhálà tí wá bái! Bí gbajúmọ̀ Òṣeré Nollywood ilẹ̀ wá, Annie Idibia, ti ṣe ohun tí gbogbo ènìyàn ń sọ nípa rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.
KÍ LÓ ṢẸLẸ̀?
Nínú Fọ́tò méjì ti osere òun gbé jáde tí ó ń fi iyàtọ̀ hàn, nínú Fọ́tò àkọ́kọ́, Annie pa orúkọ “IDIBIA” tí ó fi taato kò sí egungun ọrùn òsì rẹ̀ hàn gbangba.
Nínú Fọ́tò kejì, Annie jáde nínú aṣọ ewé olójú kan àti ṣòkòtò funfun, nígbà tí orúkọ náà ti parẹ́! Ó ti fi àwòrán labalábá dúú bò ó mọ́lẹ̀ lójú ejika rẹ̀.
KÍ NÍ LABALÁBÁ TÚ MỌ́ SÍ?
Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ń sọ pé labalábá kì í ṣe àwòrán lásán. Labalábá túmọ̀ sí:
*Ìyípadà tuntun
*Ìbẹ̀rẹ̀ tuntun
*Ominira
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló rò pé Annie fẹ́ sọ fún ayé pé òun ti bẹ̀rẹ̀ ìyé tuntun, pàápàá jùlọ ní àkókò tí gbogbo ojú wà lórí ìgbé ayé ara ẹni rẹ̀.
Títí di ìsinsìnyí, Annie kò tíì sọ̀rọ̀ kankan lórí ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwòrán tuntun rẹ̀ ti mú kí ẹ̀rọ ayélujára gbóná!
A óò tẹ̀síwájú láti tẹ̀lé ìtàn yìí. Bí ẹ bá ní ìròyìn tó wúlò, ẹ kàn sí wa ní newsroom@ojbmedias.com.ng tàbí kí ẹ pè 0806 695 2410 +2348076452810
