Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aiku, 15, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Gbajugbaja arinrin-oge Ọmọ Nàìjíríà nni, Dókítà Danielle Adewusi, tí balẹ s’iluu Dé Puerto Rico Fún Ìdíje Omidan Àgbáyé Tó Dára Jùlọ – Miss Universe 2026
Gbajugbaja ọmọ ilẹ Nàìjíríà tó gba amì-ẹyẹ Omidan Nàìjíríà fún ọdún 2026, Dr. Danielle Adewusi, ti balẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Puerto Rico lati bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ nínú ìdíje Omidan tó dára jùlọ lágbàáyé.
Danielle, tó jẹ́ aṣojú láti Ìpínlẹ̀ Èkó, dé sí olú ìlú San Juan ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹsàn-án oṣù Kọkànlá ọdún 2026, níbi tí ó ti dara pọ̀ mọ́ àwọn omidan mìíràn tí kò dín ní ọgọ́fà [120] láti orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé fún àwọn ìṣe àkọ́kọ́ kí ìdíje náà tó bẹ̀rẹ̀.

Ìdíje ọdún yìí jẹ ẹlẹ́ẹ̀karùndínlọ́gọ́rin (75th Edition), èyí tó jẹ́ ayẹyẹ Diamond Jubilee ti Miss Universe. Ayẹyẹ ìparí yóò wáyé ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù Kọkànlá, ọdún 2026, ní gbọ̀ngàn Coliseo de Puerto Rico José Miguel Agrelot ní San Juan, gbọ̀ngàn tó tóbi jùlọ ní agbègbè Caribbean.
Gẹ́gẹ́ bí àtòjọ tó jáde, àwọn ìdíje pàtàkì mẹ́ta ni yóò wáyé níbẹ̀:
Ọjọ́ kokanlelogun oṣù Kọkànlá: Ìfihàn Aṣọ Orílẹ̀-èdè (National Costume Show)
Ọjọ́ kejilelogun oṣù Kọkànlá: Ìdíje Àkọ́kọ́ (Preliminary Competition)
Ọjọ́ keerinlelogun oṣù Kọkànlá: Ìparí àti Fífi Adé Fun Ẹni Tó Borí
Danielle fúnra rẹ̀ ló kéde ìbálẹ̀ rẹ̀ lórí ikanni ayelujara rẹ̀, ó sì rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé láti ṣe àtìlẹyìn fún òun.

TAANI DANIELLE ADEWUSI GANGAN?
Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí omidan, ṣùgbọ́n ìtàn rẹ̀ jinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.
1. Oníṣègùn Tó Kàwé Gidi: Danielle kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìṣègùn ní King’s College London ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí ó ti gba oyè MBBS àti First-Class BSc nínú Psychology.
2. Ajogúnbá Adé: Ìtàn ìdílé rẹ̀ ní ìdíje ẹwà yìí dùn mọ́ni. Ìyá rẹ̀ ni Tonia Okogbenin, ẹni tó gba amì-ẹyẹ Omidan Nàìjíríà ní ọdún 1991, tó sì ṣoju Nàìjíríà ní Miss Universe ní ọdún náà. Èyí túmọ̀ sí pé lẹ́yìn ọdún 35, ọmọbinrin ti padà gbé adé náà.
3. Olùdásílẹ̀ Scrub The Stigma: Ní ọdún 2023, ó dá àjọ kan sílẹ̀ tí ó pè ní Scrub The Stigma, àjọ tó ń gbé ìlera àwọn obìnrin lárugẹ, tó ń kọ́ wọn nípa ẹ̀kọ́ ìlera ní Nàìjíríà àti ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Danielle gba adé Miss Universe Nigeria ní alẹ́ ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2026, ní gbọ̀ngàn Balmoral, Federal Palace Hotel, Victoria Island, Èkó, lẹ́yìn tí ó borí àwọn olùdíje 19 mìíràn.

Báwo Ni A Ṣe Le Dibo Fún Un? – Ẹka ‘Beyond The Crown’
Àwọn alákóso Miss Universe Organisation ti ṣí ojú òpó ìdìbò sílẹ̀ fún gbogbo ayé láti dibo fún àwọn olukopa tí ó jẹ ààyò ọkàn wọn, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Nàìjíríà lè dibo fún Danielle ní ẹ̀ka méjì pàtàkì:
1. Fan Vote / Favourite: Ẹni tó ní ìbò jùlọ yóò wọ Top 30 lọ́fẹ̀ẹ́, láìsí ìdíje mọ́. Ìbò yìí ṣe pàtàkì gan-an.
2. Beyond The Crown: Ẹ̀ka pàtàkì tó ń ṣe àfihàn iṣẹ́ ìrànlọ́wọ́ àwọn omidan. Danielle yóò lò ó láti ṣe àfihàn iṣẹ́ rẹ̀ lórí ìlera àwọn obìnrin.
BÍ Ó ṢE LÈ DIBÒ:
Lọ sí ojú òpó ayélujára missuniverseorg.com/vote tàbí gba app MU Fan App lórí Apple Store àti Google Play. Wá orúkọ Nàìjíríà, kí o sì dibo. Gbogbo ìbò ni yóò di kíkà títí di ọjọ́ ìparí.
Èyí ni àkókò fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà káàkiri àgbáyé láti dúró lẹ́yìn ọmọbìnrin wa. Láti Èkó dé San Juan, ìrìnàjò adé ayé ti bẹ̀rẹ̀!
OJB News Yorùbá yóò máa mú ìròyìn tuntun wá fún yín lórí ìdíje náà.

One thought on “Miss Universe 2026: DANIELLE ADEWUSI ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ TO GBADE ÒGO ÀGBÁYÉ GUNLẸ SILU DE PUERTO RICA”