Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú, 15, Oṣù Kọkànlá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

*Ẹmir Kánò Dé Ìbàdàn, Ó ní “Ìbàdàn Ni Ilé Kejì Mi”
Ìròyìn ayọ̀ àti ìṣọ̀kan dé láti ìlú Ìbàdàn lónìí, nígbà tí Ẹmir Kánò, Ọba Muhammadu Sanusi Lamido Sanusi II, bẹ Ààfin Olúbàdàn ti Ìbàdànland, Ọba (Senator) Rashidi Adewolu Ladoja, Arusa I, wò ní Oke-Aremo.
Ẹmir náà dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá àwọn ọmọlẹ́yìn àti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ní agogo méjìlá ọ̀sán, láti fi ìfẹ́ àti ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn Yorùbá àti Hausa hàn gbangba, kí ó sì tún mú kí ìbáṣepọ̀ náà lágbára sí i.

Nígbà tó dé Ààfin, Ẹmirì Sanusi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú inú dídùn, ó ní:
“Inú mi dùn gidigidi láti tún padà wá sí Ààfin Olúbàdàn. Mo ti ní ìbáṣepọ̀ tó súnmọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Ìbàdàn, àní kí n tó di Ẹmirì Kánò. Nítorí náà, Ìbàdàn ni ilé kejì mi.”
Ó tẹnu mọ́ ọn pé ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìlú Ìbàdàn kì í ṣe ti òde òní, bí kò ṣe ìbáṣepọ̀ àtijọ́ tó ti gbòòrò, tó sì ti jinlẹ̀.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Lẹ́yìn ìtẹ́wọ́gbà tó kún fún ayọ̀ àti ìyìn, àwọn ọba méjèèjì kọ́kọ́ lọ sí yàrá ìkọ̀kọ̀, níbi tí wọ́n ti ní ìjíròrò ìkọ̀kọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n jáde wá sí yàrá ìpàdé ńlá láti bá àwọn àlejò, àwọn oyè, àti àwọn ọmọlúàbí tó péjọ sọ̀rọ̀.

Ìbẹ̀wò yìí jẹ́ ẹ̀rí mìíràn pé àṣà àti ìṣe Yorùbá àti Hausa lè máa lọ pọ̀ ní ìfẹ́, ní àlàáfíà, àti ní ìṣọ̀kan.
OJB News Yorùbá yóò máa mú ìròyìn kíkún àti ohun tó jẹ́yọ nínú ìpàdé náà wá fún yín.
