EYI NI Ọ̀NÀ T’AGBA MÚ ẸBÍ ÀWỌN AJINIGBE KO TO DI PÉ A RÍ WỌN GBA PADÀ – Tinubu

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Ẹti, 31, Oṣù Keje 2026. 

 

*Aare so pe ijoba ko gba ipo lati tu awon omo-ogun won ti a ti mu sile ninu tubu – O pase lati so Ologun di Division Mejila lati koju ija igbe-ole

 

Aare Bola Ahmed Tinubu ti so ni ojo Bo, ni Abuja pe ijoba apapo kii se idunadura pelu awon ajinigbe to ji awon omo ile-iwe ati oluko ni Oriire, Ipinle Oyo ni osu Karun to koja, bẹni ko san owo idande kankan.

 

Nigbati o n ba asoju awon Oba alaye ni Ipinle Oyo soro ti Olubadan Ibadan, Oba Rashidi Ladoja n dari, Aare na salaye pe awon ajinigbe na bere fun owo idande nla ati pe ki ijoba tu awon omo egbe won ti o wa lati ọwọ awon ologun sile.

 

ÀÀRẸ NÁÀ NÍ :

“A ko ba odaran se adehun. Won fe ki a tu awon omo egbe odaran won ti a ti mu sile. Okan ninu awon ipo won ni yen, leyin owo ti won n beere. A si ni rara. A o ni ba odaran dunadura. Won se ipaniyan, a si ti mura lati pari ise pelu won.”

#### ÌGBÀ WO NÍ WỌN GBÀ ÀWỌN ỌMỌ NÁÀ ?

 

Tinubu so pe isẹ igbala to gba awon ti a ji naa ti o to bi ojo 56, jẹ isẹ ti o da lori oye ati imo ijinle ologun, ti o si jẹ aseyori laisi sanwo kobo kan.

 

Isẹlẹ naa waye ni ojo keedogun 15 osu Karun, 2026 nigbati awon omo ogun ti o n gbe ibọn wọle ko awon ile-iwe mẹta – Community Grammar School, Baptist Nursery and Primary School ati L.A. Primary School ni agbegbe Esiele ati Yawota ni Oriire LGA.

 

Nibe ni won ti ji to bi omo ile-iwe mokandinlogoji 39 ati oluko meje. Won pa oluko isiro kan, Michael Oyedokun, ti won si bẹ ori rẹ.

 

Isẹ igbala naa pari ni ọjọ Kẹ̀wá 10 osu Keje, 2026, pelu mimu awon ajinigbe mejo ati pipa awon miiran.

 

ÌDÍ TI TINUBU FI FẸ́ SỌ OLOGUN DI 12 DIVISION

 

Aare na fi han pe aṣẹ ti o pa laipe lati fa Ologun Nigeria lati Division 8 di Division 12 jẹ idahun taara si isẹlẹ Oriire.

“Gbogbo iṣẹlẹ n kọ wa ni ona titun. Idahun ti a fi fun ni lati so Division lati mejo di mejila, lati mu ki akoko idahun kuru, ki a si ni eyin ti a nilo lati bori ipanilaya ati janduku.”

O tun so pe ijoba yoo tun awon eso-igbe kọ, yoo si tun wọn wo, yoo tun wọn ni ihamọra, ki won ma jẹ awon ti won n lepa eran igbe nikan, sugbon ki won lepa awon odaran ninu igbo.

 

O tun tẹnumọ pe akoko ti de fun ọlọpaa ti ipinlẹ kọọkan [State Police], ṣugbọn pẹlu ofin ti yoo daabobo rẹ lọwọ ilokulo.

 

OHUN TÍ TINUBU BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ỌBA

 

Aare na ro awon Oba alaye pe ki won ba awon eeyan won soro lati maa ṣọra, ki won si maa pese ifitonileti.

“Ẹyin Oba tun ni ipa pataki lati ṣe. Ẹ sọ fun awọn eniyan wa ki wọn ṣọra gidigidi, ki wọn mọ agbegbe wọn, ki wọn si ma jabo awọn ajeji.”

O tun rọ awọn Gomina ipinlẹ pe ki wọn lo owo ipin ti apapo n fun wọn lọwọlọwọ – ti o ti di ilọpo mẹrin si marun-un – lati kọ awọn opopona, ki o le mu ki awọn ologun le wọ inu igbo ni irọrun.

 

Ninu ọrọ rẹ, Olubadan ti Ibadan, Oba Ladoja, ti o tun jẹ Alaga Igbimọ Oba ati Ijoye ni Ipinle Oyo, so pe wọn wa lati dupẹ lọwọ Aare ati awọn ologun fun igbala awọn ti a ji naa. O tun dupẹ fun atunṣe awọn opopona apapo bi Ibadan-Ijebu-Ode, Ogbomoso-Ilorin ati Badagry-Sokoto to n kọja Ibarapa ati Oke-Ogun.

 

Awon Oba miiran ti o wa ni Aafin Aare ni Olugbon Orile-Igbon, Aseyin ti Iseyin, Balogun ti Ibadanland, Soun ti Ogbomoso ati awon Oba pataki miiran ni Ipinle Oyo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.