Orisun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Rafiu Badmus, Osogbo |Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 30, Oṣu Keje 2026
*Ẹgbẹ́ òṣèlú náà fẹsùn kàn pé ọlọ́pàá ń halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ kí ìdìbò gómìnà tó ń bọ̀; ó bẹ Ààrẹ láti gbèjà àti láti mú àlàáfíà padà bọ̀ sípò ní Òṣun
Ẹgbẹ́ òṣèlú Accord ti kọ lẹ́tà ẹ̀dùn sí Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinubu àti sí Inspector General Ọlọ́pàá lórí ohun tí ó pè ní ìhalẹ, ìdẹkun àti inúnibíni tí àwọn ọlọ́pàá ń ṣe sí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Òṣun bí ìdìbò gómìnà ṣe ń súnmọ́lé.
Nínú lẹ́tà náà, ẹgbẹ́ náà kéde pé kí Ààrẹ, Olórí Àjọ DSS àti Olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ètò ààbò orílẹ̀-èdè kí wọ́n yára wọlé láti mú àlàáfíà àti ètò ìjọba padà bọ̀ sípò ní ìpínlẹ̀ náà. Wọ́n tún béèrè pé kí IG ọlọ́pàá yára gbé Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Òṣun, Ibrahim Gotan, kúrò nítorí àìlè rí dájú pé òun ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láìṣojúṣájú. ed0f
Ẹgbẹ́ Accord sọ pé “Ó tó gé!” lórí ìwà ipá àti ìfòyà tí ń pọ̀ sí i ní Òṣun.
