Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aje, 28, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

*O n beere $10 Milionu ni kootu fun ijiya ti o Jẹ lábẹ́ ìjọba ologun
Agbẹjọro a jà f’eto ọmọnìyàn ati Agbẹjọro àgbà ní Naijiria, Femi Falana SAN, ti fa Orilẹ-ede Naijiria lọ si Ile-ẹjọ Agbegbe ti ECOWAS, ẹsun kan ni pe awọn alaṣẹ ijọba lo ofin ni ilokulo lati mu un, wọn ti mọ àtìmọ́lé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, da irin-ajo rẹ duro ati ṣẹ awọn ẹtọ ọmọnìyàn rẹ labe awọn ijọba ológun, èyí tí ó wáyé lati ọdun 1980 si 1990.
Ẹjọ naa ti a fun ni nọmba ECW/CCJ/APP/30/2026 ni a gbe kalẹ ni Abuja.
Falana n fi ẹsun kan pe awọn alaṣẹ Naijiria ṣẹ ẹtọ rẹ si ominira ara-ẹni, iyi, igbọ ẹjọ to tọ, ohun-ini ati ominira lati rin irin-ajo ni oriṣiriṣi igba. O n beere ki ile-ẹjọ kede pe awọn iṣe naa jẹ aitọ ati ki o san $10 Milionu dọla fun un bi adanu.

Awọn ẹsun naa ko ti i di mimọ nipasẹ ile-ẹjọ. Falana n beere ki ile-ẹjọ ṣe ayẹwo iwa awọn alaṣẹ labẹ African Charter on Human and Peoples’ Rights ati awọn ofin ECOWAS to wulo.
IBẸRẸ ÌJÌYÀ RẸ – 1982:
Falana, ti a pe si ẹnu iṣẹ agbẹjọro ni 1982 ti o si ti jẹ Aarẹ tẹlẹ fun West African Bar Association, sọ pe wahala akọkọ rẹ bẹrẹ ni ọdun tí ó ṣe iṣẹ́ agunbaniro NYSC rẹ ni Oyo ni 1982-1983.
Gẹgẹ bi ẹjọ naa ṣe sọ, o gbe awọn akẹkọọ Yunifasiti ti Ibadan ti wọn fi ẹsun kan pe wọn fẹ pa Vice Chancellor, ni Ilu Ibadan, dide. O fi ẹsun kan pe awọn alaṣẹ NYSC gba iwe-ẹri NYSC rẹ nitori o gbe awọn akẹkọọ naa dide laisi igbanilaaye, bi ẹjọ naa tilẹ pari ni ojurere wọn – Andrew Ogor & Ors v Chief Magistrate Emmanuel Kolawole & Anor (1983) NCLR 142.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
AWỌN IMUNI TO TẸLE:
June 8, 1985: Awọn aṣoju NSO ti o ni ihamọra mu un ni Ile-ẹjọ Giga Eko, wọn wa ile-iṣẹ rẹ lai ni warrant, wọn si detain rẹ fun ọsẹ meje ni 15 Awolowo Road, Ikoyi, labẹ ipo ẹru. Wọn da a silẹ ni August 30, 1985 lẹhin igba ti IBB gba ijọba lọwọ Buhari.
April 8, 1990: O fi ẹsun kan pe SSS ji gbe e ni agogo meji oru ni ile rẹ ni Eko, wọn ko lọ si igbo ni ọna Epe, ti o fi rin titi de Epe.

October 14, 1991: SSS da a duro lati lọ si apejọ ẹtọ ọmọnìyàn ni Harare, Zimbabwe, wọn si gba passport rẹ fun oṣu mẹfa. Agbejọro Olisa Agbakoba lo ka iwe rẹ nibẹ.
May 1992: Wọn mu Falana, Dr. Beko Ransome-Kuti ati Baba Omojola. Wọn mu Falana ni May 19 ni Ile-ẹjọ Giga Eko, wọn detain rẹ ni Bar Beach, wọn gbe e lọ si Abuja ni May 21, wọn si fi si Kuje Correctional Centre. Nigbamii, Chief Gani Fawehinmi SAN naa ni wọn mu lẹhin to gbe ẹjọ lati gba wọn silẹ. Wọn fi wọn kan ẹsun iditẹ ati ifẹ lati ja ijọba Babangida wolẹ. Falana sọ pe aṣẹ ile-ẹjọ lati da a silẹ ni June 8, 1992 ko tẹle.
June 12, 1993: Lẹhin ti wọn fagile eto idibo June 12, wọn tun mu Falana, Fawehinmi ati Ransome-Kuti fun ẹsun iditẹ ati sisọ ọrọ iyapa. Wọn wa ni detension titi di August 1993.
1994 – 1998: O tun darukọ awọn imuni miiran nitori iṣẹ rẹ lori ẹjọ Ken Saro-Wiwa ati MOSOP, ati iṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ. Ni March 1998, wọn mu oun ati awọn mẹsan-an miiran lẹhin to ṣe alaye ni idanilẹkọọ oṣiṣẹ ni Ilorin.
OHUN TÍ O N BÉÈRÈ:
Falana tun tọka si iwe iranti Babangida “A Journey in Service” ti o jade ni February 2025, nibiti Babangida ti jẹwọ pe Moshood Abiola gba idibo June 12, 1993. Falana ni ijọba apapọ ko ti ṣe atunṣe tabi dariji awọn ti wọn jiya fun wi pe Abiola lo bori.
Awọn nkan ti o n beere ni Ile-ẹjọ ECOWAS ni:
Ki ile-ẹjọ kede pe awọn imuni rẹ lati 1985 si 1996 jẹ aitọ, o si tako Article 6 ti African Charter.
Pe jijigbe rẹ ni 1990 tako Article 4 ati 5.
Pe wiwọle irin-ajo rẹ ni 1991 tako Article 12.
Pe gbigba iwe NYSC ati passport rẹ tako ẹtọ ohun-ini rẹ Article 14.
Pe awọn ẹsun iditẹ ni 1992 ati 1993 tako ẹtọ rẹ si igbọ ẹjọ to tọ Article 7.
Ile-ẹjọ ECOWAS ko ti i pinnu lori awọn ẹsun naa.

One thought on “Wàhálà wá óò! FALANA GBÉ IJỌBA APAPỌ LỌ SILE ẸJỌ́ ECOWAS, Ó BÉÈRÈ FÚN 10 MILLIỌNU DOLA, OWO ITANRAN…..”