Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku, 27, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ajọ to n ri sori eto idibo ni Naijiria, INEC, ti kede erongba re lati lo imo ero agbelerọ ti a mọ si Artificial Intelligence (AI) fun eto idibo apapọ ọdun 2027 ti yoo waye ni oṣu Kin-in-ni.
Ọgbẹni Chukwuemeka Chukwu, Kọmiṣanna eto idibo ni ipinlẹ Enugu, lo sọ eyi di mimọ lasiko ti o ṣoju Ọjọgbọn Joash Amupitan, Alaga INEC, nibi ipade awọn olootu iroyin to waye ni Enugu lọpin ọsẹ.
Chukwu, to n sọrọ lọrun Amupitan, ṣalaye pe lilo AI yoo ran ajọ naa lọwọ lati dẹkun mago-mago ati iṣẹ ẹru ninu eto idibo naa.
O ni AI yoo ran INEC lọwọ lati mọ awọn ibi ti kudiẹ-kudiẹ ba wa ninu esi idibo.

BÍ INEC ṢE FẸ́ LO AI:
Ninu alaye Ọjọgbọn Amupitan, yatọ si pe INEC yoo lo AI fun idibo yii, ajọ naa tun ti mura silẹ lati dojukọ awọn to le lo imọ ẹrọ naa lati gbe awuruju jade.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Lara awọn eewu ti INEC darukọ ni:
Lilo AI lati ṣe ofege iwe esi idibo,
Lilo ayẹdẹru ohun ẹnu awọn oṣiṣẹ INEC lati kede ofege esi idibo,
Gbigbe ayẹdẹru fidio esi ibo jade,
Ati ṣiṣe ẹda pẹlẹ awọn iwe ajọ INEC.
O ni imọ ẹrọ AI ko wa lati rọpo ofin, bikoṣe lati ran ofin lọwọ fun abajade to dara.
ỌJỌGBỌN AMUPITAN SỌ BẸẸ PÉ:
“A ti ṣẹda ẹka AI si abala imọ ẹrọ wa (ICT Department), a si tun ti ṣeto rẹ lọna ti ijọba yoo fi le lo o. Bakan naa ni a ti fi to awọn ile-iṣẹ nla lagbaye bii Microsoft ati Google leti, nipa bi a ṣe le daabo bo o, eyi ti yoo dinku eewu.”
INEC tun n ṣiṣẹpọ pẹlu awọn ẹka to n kọ awọn oṣiṣẹ ni lilo AI ati ewu to rọ mọ lilo rẹ, ati ọna ti wọn le gba lo ẹrọ naa ki idibo to de.

Ṣaaju eyi, Ọjọgbọn Amupitan ti lọ si apejọ agbaye lori AI ni Ottawa, orilẹ-ede Canada, ti akori rẹ n jẹ “Global Conference on Responsible AI and Elections” to waye ni oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii. Nibẹ ni Alaga INEC ti sọrọ lori bi wọn yoo ṣe lo AI lati mu otitọ ba eto idibo ni Naijiria.
O ni idibo Naijiria nilo AI, pẹlu bi awọn to n forukọ silẹ fun idibo ṣe to miliọnu mẹtaleladọrin-un, ti ibudo idibo si to ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an.
Awọn imọ ẹrọ ti INEC ti lo tẹlẹ ni Bimodal Voter Accreditation System (BVAS) ati Result Viewing Portal (IReV).

One thought on “ÀJỌ INEC FẸ LO IMỌ Ẹ̀RỌ AI ṢE NÍBI ÈTÒ ÌDÌBÒ GBOGBOOGBO NÍ 2027”