Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Lekan Lawal, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 6, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
*Ṣé ẹ ó gbàgbé bí mo ṣe kóra mi sínú wàhálà àti ìdààmú Miista Cole àti ìyàwó rẹ̀ àti bí mo ṣe gba kaa mú ni gbeyin, ẹ jẹ ki n maa tesiwaju nínú ìtàn mi fún tí ọ̀sẹ̀ yìí.
Mo délé lọ̀sán yẹn, orí ń yí mi wìrìwìrì. Àpò owó míliọ̀nù márùn-ún náà dàbí iná lọ́wọ́ mi. Mo sá a sínú àpótí atijọ́ lábẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi, mo sì jókòó lórí kẹ̀kẹ́, mo ń ronu.
“Bí mo bá lòwó yìí, gbogbo Sango-Ọta á mọ̀ pé owó ti wọlé. Ṣùgbọ́n bí mo bá kọ̀, ìyàwó baba onílé á pa mí.”
Mo kò sùn lórú ọjọ́ náà. Bí mo ṣe di ojú ni mo ń rí ojú Mrs. Cole, mo ń gbọ́ ohùn ọkọ rẹ̀: “Agogo mẹ́jọ gbáko lọ́la alẹ́.”
ÌTÀN ÀWỌN AKỌNI
Owo rèé, ikú rèé, ìyàwó l’anloodu fún mi ní faifu millionu kí n fún lóyún apá kinni ìtàn aládùn
Ọjọ́ kejì, agogo méje ìrọ̀lẹ́
Tẹlifóònù mi bẹ̀rẹ̀ sí dún. Number tí mi ò mọ. Mo gbé e:
“Joseph, má ṣe gbàgbé o. Agogo mẹ́jọ gbáko. Bí o kò bá dé, o mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.” Ó jẹ́ ohùn Mrs. Cole. Ó dá ìpè náà dúró.
Ní ọwọ asalẹ, mo ti ronú ronú, mo yà gba ká mú pé owo rèé, ikú rèé, ṣugbọn mo mọ pe ìyè ni mo yàn láṣẹ Èdùmàrè.
Ẹ̀jẹ̀ mi gbóná. Mo wọ ṣòkòtò dúdú, mo wọ fila láti bo ojú mi. Bí mo ṣe ń lọ sí ilé baba onílé, gbogbo Sango dàbí ẹni pé wọ́n ń wò mí.
Mo kan lẹ̀kùn, baba onílé gan-an ló ṣí lẹ̀kùn. Ó ń rẹ́rìn músẹ́, ó wọ aṣọ ìsìnà bí ẹni pé òun ń lọ sí ìjọ.
“Joseph ọmọ mi, o dé ní àsìkò. Ìyàwó mi ń retí ẹ nínú yàrá. Ẹ má ṣe yára o, ẹ ṣe é dáadáa.” Ó fọwọ́ tẹ̀ mí lẹ́yìn, ó sì lọ jókòó ní pálọ̀, ó ń wo Super Story lórí NTA.
Mo wọ yàrá, Mrs. Cole ti wà lórí bẹ́ẹ̀dì. Lórí tábílì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ, àpò owó mìíràn wà — míliọ̀nù márùn-ún kejì.
“Sẹ́ o ti rí i pé àwa kì í ṣe aláìní?” Ó sọ, ó ń yọ eyín. “Míliọ̀nù márùn-ún fún ìgbà kọ̀ọ̀kan. Títí tí mo fi lóyún.”
“Anti, ẹ jọ̀ọ́,” mo bẹ̀rẹ̀ sí bẹ ẹ̀. “Kí ló dé tí ọkọ ẹ kò fi lè ṣe é? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí yín?” Ojú ẹ̀ yí padà. Ó dìde kánkán, ó di ọwọ́ mi mú gbáù.
“O pọ̀jù béèrè, Joseph. Ṣe iṣẹ́ tí a fẹ́ ṣe, kí o sì gbé owó ẹ. Bí o bá tẹ̀ ẹnu bọ́ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́nu níta, Sango-Ọta kò ní gbé ẹ mọ́. Àwa ló ni ọlọ́pàá, àwa ló ni oníròyìn. O gbọ́?”
Inú mi kọ. Èyí ti kọjá ti Joseph àti Pọ́tífárí. Èyí ti dàbí ère ẹgẹ́lẹ apànìyàn.
“Ṣùgbọ́n anti, àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀…”Mo ní ká ṣe é nísìnyí!” Ó hó, ó ti fa ṣẹ́ẹ̀tì mi ya.
Nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn ẹsẹ̀ ní ẹ̀yìn odi. Ẹnìkan ń gbọ́ wa. Mo wo ojú fèrèsé, mo rí òjìji ọkùnrin kan tó ń ya fọ́tò wa láti ìta. Kódàkódà ìyàwó baba onílé ò rí i.
Mo pa mí mọ́ra. “Anti, ẹnìkan wà níta ń ya wa!”
Ó yára bọ́ sí fèrèsé, ó wo. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ojú ẹ̀ pupa.
“Ṣọ́lá! Ọmọ yẹn náà tún dé o!” Ó kígbe. “Ọ̀gbẹ́ni Cole, wá báyìí!”
Baba onílé jáde wọ yàrá bí ìjì. Kò rẹ́rìn mọ́. Ojú ẹ̀ ti burú.
“Ṣọ́lá náà? Ó tún ń tọpinpin wa? Joseph, gbé aṣọ ẹ, ẹ jẹ́ ká lọ.”
“Ṣọ́lá ta ni, sir?” Mo bi pẹ̀lú ẹ̀rù.
“Ọ̀tá ilé. Ó fẹ́ ba ètò wa jẹ́. Bí ó bá tú ọ̀rọ̀ yìí síta, míliọ̀nù mẹ́wàá tí a ti gbà lọ́wọ́ àwọn òyìnbó fún ‘ìwádìí’ yìí á di òfò.”
Háà! Nígbà yẹn ni mo mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọmọ nìkan.
Ìdí mi ti domi, oògùn ara bomi, hmm, mi ò mọ ibi tí mo wà mọ ayé tí sumi.
E je ki a dànù dúró náà, kí a tesiwaju nínú ìtàn mi.
A máa mú itẹ̀síwájú apá kẹrin wá laipẹ…
Follow the OJB MEDIA HUB channel on WhatsApp: https://whatsapp.com/channel/0029Va8RpCj8fewvCADtHd0K
Follow the OJB MEDIA HUB page, like and comment. click on the link below : https://www.facebook.com/oojiirebimediashub
