OWO RÈÉ IKÚ RÈÉ, IYAWO L’ANLỌỌ́DU FÚN MÍ NI FÀÌFUU MILIONU, KI N FÚN LÓYÚN (Apá Keji)

Orísun: OJB News Yoruba | Onkotan: Lekan Lawal, Sango-ọ̀tá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú 2, Oṣù Kẹjọ 2026. 

 

Nínú apá kinni ni mo ṣe sọ bí Ìyàwó baba onílé mi ṣe ma ń gbé pátá rẹ̀ kalẹ̀ ní ẹnu-ọ̀nà mi láàrọ̀ ọjọ kọ̀ọ̀kan. Mo sì sọ bí mo ṣe kó gbogbo rẹ jọ pọ tí sì gbé e lọ sí yàrá rẹ̀ láti dá padà, ọkọ rẹ̀ ló ṣí lẹ̀kùn fún mi, ó ní kí n sọ ìyàwó ẹ̀ di aboyún fún míliọ̀nù márùn-ún náírà.

Ní bẹẹ ni mo dànù dúró sí nínú apá kinni, ẹ jẹ ká fara balẹ fún tí ọ̀tẹ̀ yìí.

 

Háà! Ara tú mi lọ̀gàn.

“Joseph, míliọ̀nù márùn-ún ná ni,” baba onílé mi lo sọ bẹẹ, ó ń wò mí lójú gan-an. “Fún ìyàwó mi lọmọ. A ó ṣe é níhìn-ín lóníì. Èmi á lọ jókòó ní pálọ̀ kí o tó parí iṣẹ́ ẹ.”

Mo dúró gbọ́ọ́, orí mi dàrú. Kí n tó lè sọ̀rọ̀ kan, Ọ̀gbẹ́ni Cole ti jáde kúrò nínú yàrá, ó ti lẹ̀kùn pa, ìyàwó ẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí tú aṣọ ìwẹ̀ ẹ̀ sílẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́.

“Anti, ẹ jọ̀ọ́! Ẹ ro aṣọ yẹn mọ́ra pada,” mo kígbe,

Bẹ́ẹ̀ ni, míliọ̀nù márùn-ún fún ọmọkùnrin tí ìṣẹ́ ń jẹ bí èmi, owó ìgbé ayé ni. Ó lè yanjú gbogbo wàhálà mi. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo rántí Joseph tòótọ́ inú Bíbéli, mo mọ̀ pé ère egele ikú ni.

“Sẹ́ o ń bẹ̀rù ni, Joseph?” Mrs. Cole sọ lọ́rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́, ó ń sún mọ́ mi.

“Ma, èyí ti ju èrè lọ,” mo ṣáre sọrọ. “Ọkùnrin wo ló máa jẹ́ kí ọmọkùnrin mìíràn fọwọ́ kàn ìyàwó òun, kí òun náà sì máa wò telifisan NTA lẹ́yìn odi? Kò lè rọrùn bẹẹ rara.”

“Kò ní pa ẹ́, Joseph. Ìgbóná ọkàn ló ń ṣe ẹ́,” ó sọ. “Ṣùgbọ́n bí o bá gbìyànjú láti gbéra kúrò níbì láì ṣe iṣẹ́ yìí… níbẹ̀ ni wàhálà yóò ti hù jáde fún ọ.”

ÌTÀN ÀWỌN AKỌNI 

Owo rèé, ikú rèé, ìyàwó l’anloodu fún mi ní faifu millionu kí n fún lóyún apá kinni ìtàn aládùn

“Mi ò gbọ́, ma. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?” Mo bi í.

“Ònà méjì ló wà fún ọ,” ó sọ. “Kí o wá sùn pẹlu mi lórí bẹ́ẹ̀dì yìí, kí ó fún mi ní ohun tí mo fẹ́, kí o sì gbé míliọ̀nù márùn-ún yìí. Tàbí…”

Ó dákẹ́, ó yọ eyín funfun.

“…Tàbí kí n kígbẹ lóhùn rárá nísìnyí, kí n dá yàrá yìí rú, kí á sì sọ fún gbogbo ará Sango-Ọta pé o wọlé láti fipá bá mi lò. Tí táá ni wọ́n máa gbàgbọ́ láàrin àwa méjì?”

“Yée!” Mo kígbe. Joseph àti ìyàwó Pọ́tífárí ti tún dé bá wa ní Sango-Ọta o.

“O ní ìṣẹ́jú àádọ́ta láti yan,” ó sọ, ó ń sún mọ́ mi síi.

 

“Ṣùgbọ́n anti,” mo dá a lẹ́nu kọ́. “Bí a bá fẹ́ ṣe èyí, ká kọ́kọ́ lọ sí laabù. A ní láti ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ wá. HIV, Hepatitis, gbogbo rẹ̀. Ká mọ̀ pé àwa méjèèjì mọ́.”

Gbàrà tí mo sọ bẹ́ẹ̀, ojú ẹ̀ yí padà gidi. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bá a.

“Àyẹ̀wò kín là? Sẹ́ o ń pè mí ní aláìmọ́ ni? Tàbí o ń sọ pé èmi àti ọkọ mi ní àrùn?!”

“Rárá o, ma. Ìlànà lásán ni mo ní kí a tẹle.”

“Gbé ẹnu ẹ dákẹ́!” ó ń sùn mọ mi, ó fa ṣẹ́ẹ̀tì mi. “A ò ní àkókò fún àyẹ̀wò òmùgọ̀ kankan. Ká ṣe é nísìnyí.”

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí fura nínú ọkàn mi. Kí ló dé tí ó fi ń sáré báyìí? Àbí àrùn olóró kan wà tí ó ń fi pamọ́? Ìdí nìyẹn tí ọkọ ẹ̀ kò fi ń sùn mọ́ ọn ni?

Ṣùgbọ́n nígbà tí mo wo míliọ̀nù márùn-ún tí ó wà lórí bẹ́ẹ̀dì, mo rántí bí ìṣẹ́ ṣe ń ba mí fínra ní Sango. Kí ni èyí tí ó burú jù?

Lójú ẹsẹ ni mo ṣe ọkàn akin “Ó yá, mo gbà,” mo sọ, pẹlu ìgboyà.

Ó rẹ́rìn, ó sì fa mí mọ́ra nígbà tí ó ju aṣọ aromọya ìwẹ̀ rẹ náà nù.

 

***

  1. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú medogbon:

Nígbà tí a parí, ó kan dìde, ó wọ yàrá ìwẹ̀, ó gbàgbé mi patapata.

Ara mi ń wárìrì gbígbí. Mo yára wọ ṣòkòtò mi, mo gbé àpò owó náà, mo sọ sínú ṣòkòtò.

Mo ṣi lẹ̀kùn yàrá, mo jáde lọ sí pálọ̀, mo ń rò pé èmi ni ẹlẹ́ṣẹ̀ jù lọ ní gbogbo Sango-Ọta wá àti lagbaye.

Baba onílé mi jókòó lórí ṣófà, ó ń mu tíì gbígbóná, ó ń wo ìròyìn. Ara rẹ balẹ̀ gan-an.

 

Ó YÍ ORÍ PADÀ, Ó WO MÍ.

“Sẹ́ o ti parí, Joseph?” ó bí mi lóhùn ẹ́nu tutù, ó ń mu tíì ẹ̀.

“Ẹ̀-ẹ̀-ẹn sir. Mo ń lọ níyẹn, sir,” mo dáhùn, ẹsẹ̀ rẹ ń mì.

“Ó dára,” Ọ̀gbẹ́ni Cole sọ, ó gbé ife tíì ẹ̀ kalẹ̀. “Rí i dájú pé o sinmi dáadáa lóníì. Mo ń retí ẹ lọ́la alẹ́ ní agogo mẹ́jọ gbáko nínú yàrá ìyàwó mi. Ẹ̀ẹ̀kan kò tó láti lóyún.”

 

A máa mú itẹ̀síwájú apá kẹta wá laipẹ…

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.