ỌPẸ Ó! TINUBU TÍ NI KI WỌN Ò TÀ ÀWỌN ILÉ TÍ EFCC GB’ẸSẸ LE NI GBANJO

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 19, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Wọn joko sọrọ lori awọn ile ti EFCC ti gba lọwọ awọn eniyan ti wọn ji owo orilẹ-ede kò sapo ara wọn. Iroyin ni pe wọn fẹ ta awọn ile yẹn, ṣugbọn wọn fẹ ṣe e ni ọna ti yoo hàn sí gbogbo aráyé, ki gbogbo eniyan le mọ bi owo rẹ ṣe lọ, ko si má sì mago-mago.

 

Eyii túmọ̀ sí pé kí wọn ó ṣètò bí ilé náà yóò ṣe jẹ́ títa ni gbanjo fún ara ìlú, dípò tí àwọn ilé náà yóò fi bajẹ sórí ìdúró, àṣẹ ìròyìn náà jáde láti olú ileeṣẹ ọba ní Abuja ni o fi fọto ipade naa sita ni Tuesday.

Ààrẹ Tinubu, pẹlu ọga àjọ EFCC Olukoyede àti Muqattar Darmma tí ó jẹ minisita ọrọ ilegbe níbi ipade

Kini o fa ipade yii?

Ẹ ranti pe ni August 5, EFCC ti lọ di akanti owo Ipinlẹ Osun, wọn ni awọn oga Osun ti fọwọkan owo N11bn ti o jẹ ti isakoso iṣẹlẹ ayika.

 

Osun lọ si ile-ẹjọ, wọn ni EFCC n ṣe wọn ni ibi.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Ṣé lóòótọ́ nipe Ogogo kú?, eyii ni òun ti a mọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ

Ọ̀tẹ àti Tembelekun Ààrẹ Kunrunmi tó fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ jagun, tó sì kú sójú ogún, bẹẹni kò jèrè ogún, àwọn ọmọ rẹ maar’arun loku s’ogun

Raa káàdì ìpè rẹ tàbí kí ó sanwó sórí DStv àti Gotv rẹ, bẹẹ naa ni o le ra Data pẹlu kí ó sì fi owó sórí Prepaid meter rẹ pẹlu irọrun lọdọ wá lónìí, tẹ asopo yìí

Aarẹ Tinubu funra rẹ ni o pe EFCC, o ni “ẹ yọ akanti Osun silẹ, akoko ti ẹ di i ko dara, o sunmọ idibo gomina lọpọlọpọ.”

Idibo naa ti pari, Adeleke ti wọle.

Adeleke funra rẹ sọ lori Channels TV pe:

“Mo ti sọ fun Attorney General mi pe ko yọ ẹjọ EFCC kuro. Baba Tinubu ti pe mi, ti ṣe daadaa. Kini mo tun fẹ?”

Ipade ti wọn ṣe ni Tuesday yii waye ni ọjọ mẹta lẹhin ti Adeleke wọle tan.

 

Ni kukuru, Tinubu ni ki wọn ta awọn ile ti a gba lọwọ awọn ole, ṣugbọn ki wọn ṣe e ni ọna titọ, ki owo naa ma ṣe padanu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.