Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Sango-Ọta| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ 20, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Iroyin kan ti jade pe Pastor Chris Oyakhilome ti Christ Embassy ti kede pe ijọ naa ti bẹrẹ si ṣe Ọkọ tó nlo ina (electric cars).
Sugbọn ibeere ofin nla kan wa nibe:
Ṣe ile ijọsin ti a forukọsilẹ gẹgẹ bi “Incorporated Trustee” le lọ ṣe iṣẹ ṣiṣe ọkọ bi ile-iṣẹ ti n wa owo?
Gẹgẹ bi ofin Naijiria:
1. Incorporated Trustee kii ṣe Limited Company. Trustee jẹ fun iṣẹ ẹsin, aanu ati iranlọwọ, kii ṣe fun pinpin ere.
2. Ṣiṣe ọkọ jẹ ileeṣẹ ti o ni ilana pupọ – o nilo NADDC, SON, CAC ati awọn ajọ miran.
3. Trustee le ri owo wọle, ṣugbọn a ko da a silẹ lati ṣe owo bi ile-iṣẹ.
Nitorinaa ibeere pataki ni:
Ṣe Christ Embassy tikarẹ ni o n ṣe ọkọ naa, tabi wọn ti da ile-iṣẹ ọtọ silẹ fun ọkọ naa?
Ti o ba jẹ ile-iṣẹ ọtọ:
* Tani ni oluwa ile-iṣẹ naa?
* Tani o na owo si?
* Kini asopọ rẹ pẹlu Christ Embassy?
Eyi ni ohun ti ofin yoo fẹ mọ! A n duro de alaye siwaju sii.
Kini ero yin? Ẹ sọ fun wa ninu comment!
