*Ọ̀pọ̀ ènìyàn ti yí ọ̀rọ̀ tí LASERC kọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára wọn padà.
*Gbogbo gbèsè owó Ina àtijọ́ rẹ lo gbodo san án padà
Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Hafsat Temitope Lawal, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ 6, Oṣù Kẹjọ 2026.
Ilé-iṣẹ tó ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ iná ní Ìpínlẹ̀ Èkó, LASERC, ti ṣe àlàyé kíkún pé òfin tuntun tí ó ń fa ariwo pé kí ilé-iṣẹ́ iná má gba owó iná tí ó ti kọjá oṣù 12, kò túmọ̀ sí pé gbèsè iná àtijọ́ yóò parẹ́.
Gẹ́gẹ́ bí OJB MEDIA HUB ṣe rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti yí ọ̀rọ̀ tí LASERC kọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára wọn padà. Wọ́n ti kọ pé “Licensees cannot recover charges older than 12 months”, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ló rò pé gbogbo gbèsè ti parẹ́.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Se lóòótọ́ ni pé àjọ EFCC létí àpò àsùnwọ̀n ìjọba ipinlẹ kàn pa https://ojbmediashub.com.ng/blog/%e1%b9%a3e-efcc-leto-lati-da-apo-asunwon-ipinle-duro-bi-kin-lofin-so/
Eyii ni òun ti a mọ nípa àwọn tí wọn gba padà lọ́wọ́ àwọn Bandiiti ni ipinlẹ Kwara https://ojbmediashub.com.ng/blog/ope-o-won-ti-gba-awon-tawon-bandiiti-ji-ko-ni-ipinle-kwara-pada/
LASERC sọ pé irọ́ ni. Òfin náà wà ní Paragraph 12 ti Retail Electricity Supply Code tuntun, ó sì jẹ́ ti ọjọ́ iwájú nìkan. Gbogbo gbèsè tí ó ti wà ṣáájú kí koodu náà tó bẹ̀rẹ̀, gbọ́dọ̀ san.
Olórí LASERC, Mrs. Temitope George, sọ pé ète òfin náà ni láti mú kí àwọn DISCOs ṣiṣẹ́ dáadáa, kí wọ́n má ṣe máa kó owó oṣù púpọ̀ jọ.
Nítorí náà, bí o bá ní gbèsè àtijọ́, o ṣi ní láti san án.
Ka si si lori OJB MEDIA HUB – www.ojbmediahub.com.ng
