ṢÉ EFCC LẸTỌ LÁTI DÁ APO ÀSÙNWỌ̀N ÌPÍNLẸ̀ DÚRÓ BÍ, KIN L’OFIN SỌ

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ 6, Oṣù Kẹjọ 2026. 

 

Gẹgẹ bi ìwé ìròyìn OJB News Yorùbá ṣe royin, Ajọ to n ja tako iwa ibajẹ ọrọ-aje, EFCC ti paṣẹ fun ile ifowopamo tí First Bank Plc lati fi aami PND (Post-No-Debit) si akọọlẹ owó Allocation ti Ijọba Ipinlẹ Ọṣun, gẹgẹ bi apakan iwadii ti wọn n ṣe, ni ọjọ mẹwaa pere si idibo Gomina to n bọ ni ọjọ 15 Oṣu Kẹjọ 2026.

 

Lẹta naa ti o ni àkọsílẹ̀ ọjọ karùn-ún (5) Oṣu Kẹjọ 2026 ti Adenike Babalola, Assistant Commander of EFCC fọwọ si fun Director of Investigation, ni a kọ si MD First Bank.

 

KÍNNÍ PND TUMỌ SÌ? 

PND tumọ si pe wọn ko ni jẹ ki owo kankan jade ninu akọọlẹ naa, ṣugbọn owo le wọle. Idi ni lati ma jẹ ki owo ti wọn fura si ma lọ titi ti iwadii yoo fi pari.

 

Ṣé EFCC ní agbára lati di akọọlẹ Ijọba Ipinlẹ lẹkun?

Idahun ni BẸẸNI, ṣugbọn labẹ ofin nikan.

1. Agbara Igba Diẹ: Labẹ Abala 34(1) ti Ofin EFCC Act 2004, Alaga EFCC tabi oṣiṣẹ ti a fun ni aṣẹ le, ti o ba ni idaniloju pe owo inu akọọlẹ kan jẹ abajade iwa ọdaràn, beere lọwọ ile-ẹjọ tabi paṣẹ fun banki lati di akọọlẹ naa mu fun igba diẹ fun iwadii.

 

2. Agbara Ko Lopin: Ṣugbọn agbara naa ko lopin. Ti EFCC ba fẹ ki akọọlẹ naa wa ni didi fun igba pipẹ, dandan ni ki wọn gba aṣẹ ile-ẹjọ giga Federal High Court. Dídì akọọlẹ fun igba pipẹ laisi aṣẹ ile-ẹjọ le jẹ ki ẹnikẹni lọ si ile-ẹjọ lati koju rẹ. 3. Akọọlẹ Ijọba kọ ni a ko le fọwọ kan: Otitọ pe akọọlẹ naa jẹ ti Ijọba Ipinlẹ ko tumọ si pe a ko le ṣe iwadii rẹ. Bi ẹsun iwa ibajẹ ba wa, EFCC le ṣe iwadii. Ṣugbọn o gbọdọ ṣe laarin ofin ati Constitution.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ :

*Wọn ti ṣe ìgbà kalẹ àwọn tí àwọn ajinigbe bandiiti ji gbé ní Kwara https://ojbmediashub.com.ng/blog/ope-o-won-ti-gba-awon-tawon-bandiiti-ji-ko-ni-ipinle-kwara-pada/

*Àwọn ọmọ ogun ikọ operation Hadin Kai tí ṣe àṣeyọrí lórí àwọn apanilaya ISWAP https://ojbmediashub.com.ng/blog/awon-omo-ogun-operations-hadin-kai-%e1%b9%a3a%e1%b9%a3eyori-lori-awon-bandiiti-iswap/

Ijọba Ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe igbesẹ yii jọ ti oṣelu, nitori idibo Gomina ti n bọ, lakoko ti APC ti Ipinlẹ Ọṣun ti n beere tẹlẹ pe ki EFCC di akọọlẹ naa lẹkun lori ẹsun ₦13.7bn ghost workers.

 

Nitorinaa, ti Ijọba Ọṣun ba pinnu lati koju paṣẹ EFCC naa ni ile-ẹjọ, ile-ẹjọ yoo pinnu boya EFCC tẹle ofin ṣaaju ki o to paṣẹ fun First Bank lati di akọọlẹ naa lẹkun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.