NÀÌJÍRÍÀ NILO OLÓRÍ TUNTUN TORÍ TINUBU TÍ KÙNÀ LÁTI MÚ INÚ ARÁ ÌLÚ DUN-Obi

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abújá | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Ajé, 27 July, 2026

 

Aṣáájú ẹgbẹ́ Labour Party àti olùdíje fún ipò Ààrẹ ní ètò ìdìbò tó kọjá, Peter Gregory Obi, ti tún ṣí ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ lórí ipo orílẹ̀-èdè Naijiria.

Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní ìpàdé àwọn oníròyìn, Obi rọ Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti ronú jinlẹ̀ kí ó fi ipò silẹ̀ fún ẹni tó ní agbára àti ìmọ̀ tó pọ̀ jù.

 

GẸ́GẸ́ BÍ OBI ṢE SỌ:

“Ohun tí a n rí lónìí ní Naijiria fihàn pé a nílò olórí tuntun pátápátá. Ọrọ̀ ajé ti bàjẹ́, ebi ń pa àwọn ènìyàn, ààbò kò sí mọ́. Ó hàn gbangba pé Ààrẹ Tinubu kò ní agbára tó pọ̀ tó láti mú orílẹ̀-èdè yìí jáde kúrò nínú ìṣòro tó wà.”

 

Obi tẹ̀síwájú pé bí owó náírà ṣe ń ṣubú, bí oúnjẹ ṣe ń wọ́n, àti bí àwọn ọ̀daràn ṣe ń jí àwọn ènìyàn gbé lójoojúmọ́ ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé ìjọba kò ṣiṣẹ́.

Ó ní, kò sí ìkórìíra nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, bí kò ṣe pé òtítọ́ ni òun ń sọ fún ààbò ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ Naijiria.

Títí di àsìkò yìí, ilé iṣẹ́ Ààrẹ kò tíì dáhùn sí ọ̀rọ̀ Peter Obi yìí.

Kí ni èrò yín? Ṣé ó yẹ kí Tinubu fi ipò silẹ̀ bí Obi ṣe sọ, tàbí kí ó tẹ̀síwájú?

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ sọ èrò yín nínú comment, kí ẹ sì tẹ follow OJB NEWS YORUBA fún ìròyìn tó gbóná jùlọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.