GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ YORUBA NNÌ, TAIWO HASSAN OGOGO TÍ JÁDE L’AYE

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Àìkú, 23, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Inu ọfọ pẹlu idamu nla ni a fi n kede iku gbajumọ oṣere tiata Yorùbá, Taiwo Hassan, ti gbogbo eniyan mọ si Ogogo, ti o jade laye ni ọmọ ọdun Merindinlaadorin (66.)

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

Owo rèé, ikú rèé, ìyàwó l’anloodu fún mi ní faifu millionu kí n fún lóyún apá ká àrùn

Ajagunfeyinti Ibrahim Badmus Babangida ń pá lórí lori ọrọ June 12, àti ikú Jagunjagun Mamman Vasta ọrẹ minu rẹ

Oloye Olusegun Okikiola Matthew Aremu Obasanjo tí sọ̀rọ̀ sókè níbi ifọrọwerọ kàn nilu Bauchi laipẹ yìí ló ti ní kó tíì sí ìjọba àwa a rawa ni gbogbo ilẹ̀ Afrika bayi

BAWO NI O ṢE KU?

Ogogo jade laye lẹhin to ti kọkọ ba aisan jẹjẹrẹ (cancer) firan fun igba pipẹ.

Ọmọ rẹ obinrin, Kira Taiwo, lo fi ikede iku rẹ sita ni irọlẹ ọjọ Aiku (Sunday) loju opo Instagram rẹ.

Lẹyin naa ni agba oṣere miiran, Saheed Balogun tun ikede naa sita, nibi ti o ti sọ pe:

“Inna lillahi wa inna ilayhi raji’un. O le sinmi bayi arakunrin mi, Taiwo Hassan Ogogo. Ki Ọlọrun tẹ ọ si afẹfẹ rere.”

ẸBẸ TI AWỌN ỌMỌ RẸ ṢE SAAJU IKU RẸ:

Ti ẹ ko ba gbagbe, aarọ ọjọ Iṣẹgun (Tuesday) to kọja la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ọmọbinrin gbajumọ oṣere naa, Shakira ati Haleemah Taiwo fi igbe bọnu lori ayelujara pe aisan jẹjẹrẹ n ṣe baba wọn.

Lẹyin ikede naa ni wọn wa n beere fun iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria ki baba wọn le gba iwosan, ti wọn si n ke si awọn onisegun oyinbo ati ti ibilẹ to ba le wo baba wọn san lati jade wa.

Wọn mu u wọle si operating theatre ni ọjọ 20 Oṣu Kẹjọ, awọn agba bi Jide Kosoko, Yinka Quadri, Madam Saje si ṣe adura fun un, ṣugbọn Olorun pe e lọ loni.

Alhaji Taiwo Hassan Ogogo ṣáájú kí Ọlọjọ tó dé

AWỌN ERE TI OGOGO TI KOPA (ÀṢÀYÀN):

Taiwo Hassan Ogogo wọ agbada ati fila — o ti ṣe aami nla ni Nollywood:

Atitebi (1994)

Agbelebu (1995)

Agbo-Odaju (1995)

Owo Blow Part 2,3 (1996) – oun ni Wole Owolabi

Omin (2008) – o ṣe Adesina

Elewon (2009) – o ṣe Yomi

Omo Ghetto (2010) – as D.P.O

Aye O (2016) – o ṣe Faniyi

Ọjọ Ẹyẹ Mi (My Joyous Day) (2016)

Tenant of the House (2019) – o ṣe Hon. Kasali

Amerah (2021) – o ṣe Alhaji

Aníkúlápó (2022) – o ṣe Alaafin Ademuyiwa

Bank Alert (2023) – o ṣe Baba Agba

IGE – the unlikely oil merchant (2023) – oun lo ṣe Olalere

Anikulapo: Rise of the Spectre (2024) – o ṣe Alaafin Ademuyiwa

OJB News Yorùbá n ki gbogbo ẹbi Hassan, awọn ọmọ rẹ Shakira, Haleemah, Kira, ati gbogbo ile iṣẹ tiata Yorùbá ni a dupẹ. Ki ẹmi rẹ ma sun ni afẹfẹ rere.

A o mu alaye isinku wa fun yin laipẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.