Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aiku 23, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Sẹnatọ Solomon Olamilekan Adeola, FCA (APC, Ogun West), ẹni ti o n dije fun ipo Gomina labẹ ẹgbẹ All Progressives Congress, APC, ti ṣalaye ibanujẹ ati aibalẹ nla lori iku Ọgbẹni Taiwo Babatunde Hassan lẹhin aisan to ṣe.
Ninu ọrọ ifẹ ọkan ti o fi ranṣẹ si ebi olóògbé oṣere olokiki naa, Sẹnatọ naa sọ pe iku Hassan ti awọn ololufẹ rẹ n pe ni Ogogo jẹ adanu nla si ile-iṣẹ ẹda ati ere idaraya, o si tẹnu mọ ọn pe iku rẹ ni asiko yii jẹ adanu si ebi rẹ, si Ipinlẹ Ogun ati si Naijiria lapapọ.
“Inu mi bajẹ gidigidi lori iku arakunrin kan ti o gbagbọ ninu mi, ti o si ṣiṣẹ takuntakun fun idi mi ati idi awọn eniyan wa. Mo ba ebi rẹ kẹdun gidigidi fun igbiyanju ati ija ti wọn ja lati pa ẹmi ololufẹ wa mọ lẹhin aisan rẹ. Ọlọrun ni O mọ ohun ti o dara ju ni gbogbo ipo,” Sẹnatọ naa sọ.
Sẹnatọ Adeola sọ pe ipa ti olóògbé naa ko ninu igbiyanju fun awujọ to dara nipasẹ ṣiṣe fiimu ati igbiyanju rere miiran ni a o ma ranti nigbagbogbo, o si fi ogún silẹ ti o tọ lati fara wé.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ
Gbajumọ osere nnì, Taiwo Hassan Ogogo tí jáde láyé o
Sẹnatọ naa ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin fun ebi rẹ ti o ku sẹhin ni asiko ipọnju yii, o si sọ pe iṣẹ rere ti baba ẹbi naa ṣe si awujọ ni a ki yoo gbagbe rara.
Sẹnatọ Adeola gbadura fun isinmi alaafia fun ọkàn akọrin naa ati agbara fun ebi rẹ ti o sunmọ julọ lati farada adanu ti ko ṣe atunṣe ti ololufẹ ti o lọ.
