Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Iṣẹgun 4, Oṣù Kẹjọ 2026.
Egbe oṣelu All Progressives Congress (APC) ni Ipinle Osun, paapaa julo Igbimọ Ipolongo Gomina (Governorship Campaign Council), ti fi ibinu nla tako ohun ti wọn pe ni ọrọ ti ko ni ero, ti o n ru rudurudu soke ati ti o tako ijọba – “reckless, inflammatory and seditious” ti Gomina Ademola Adeleke sọ si Aarẹ Bola Ahmed Tinubu.
Gẹgẹ bi alaye ti o wa, Gomina Adeleke sọ ọrọ naa ni ojo Aje, nigba ti o n ba awọn ololufẹ ẹgbẹ rẹ sọrọ ninu eto ipolongo kan ni Osogbo.
AFIWE ÌRÒYÌN
Ileeṣẹ Ọlọpa tí bẹ̀rẹ̀ iwadi lórí ẹsun tí VeryDarkMan fi kàn ọga Ọlọpa AIG Moshood Jimoh
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ APC Osun, Hon. Kola Olabisi fọwọ si, ẹgbẹ naa ni ọrọ Gomina naa kii ṣe ọrọ ti o yẹ fun ẹni ti o jẹ Gomina, o si le da idarudapọ silẹ laarin awọn ara ilu. Wọn ni Gomina yẹ ki o fi ọlá fun ọfiisi Aarẹ orilẹ-ede, dipo ki o ma sọ ọrọ ti o le fa ija.
APC Osun gba awọn ara Osun niyanju lati yọ ẹnu kuro ninu ọrọ iru e, ati lati tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin fun ijọba Aarẹ Tinubu ni ipilẹṣẹ rẹ lati tun orilẹ-ede Naijiria ṣe.
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii, ẹgbẹ PDP ati ijọba Ipinle Osun ko ti dahun si ẹsun naa.
