Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Abameta 01, Oṣù Kẹjọ 2026.
*Ọ̀rọ̀ bọ́ọ̀lù ò kì í ṣe nípa iye ènìyàn tó wà lórí pápá, ọ̀rọ̀ ọkàn ni!
Lóníì yìí, nígbà tí gbogbo ayé rò pé ọjọ́ burúkú ti dé bá Tottenham, tí wọ́n sì ti pèsè sílẹ̀ láti sọkún pẹ̀lú wọn, àwọn ọmọ Spurs fi ọkàn líle hàn.
BÍ ERÉ NÁÀ ṢE LỌ :
Ìbẹ̀rẹ̀ eré kò rọrùn rárá. Chelsea wọlé pẹ̀lú agbára, wọ́n ń tẹ mọ́lẹ̀, wọ́n ń ṣe bí ẹni pé àwọn ni oluwa pápá.
Ṣùgbọ́n ogun ló bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí adájọ́ fa kaadi pupa fun Tottenham! Gbogbo pápá fó, àwọn olólùfẹ́ Spurs di dákẹ́. Ẹnìkan ti kúrò, wọ́n kù ní mẹ́wàá pere.
GBOGBO ÈNÌYÀN RÒ PÉ : “Ó TÁN !”
Sugbon ti Tottenham, iru asiko yii ni won ma n ji dide.
Láìpẹ́ lẹ́yìn kaadi pupa náà, Tottenham kò wo ẹ̀yìn mọ́, wọ́n pọ́ ọkàn wọn pọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi iyà jẹ Chelsea. Wọ́n fi agbára mẹ́wàá ṣe iṣẹ́ mọ́kànlá.
Wọ́n kọ́kọ́ wọlé kan, gbogbo stadium wó lulẹ̀!
Chelsea gbìyànjú láti dọ́gba, wọ́n sì rí ọ̀kan, ṣùgbọ́n Tottenham ní: Rárá, òní kì í ṣe ọjọ́ yín.
Ní ìṣẹ́jú ìkẹyìn tí ẹ̀mí ń bọ, Tottenham fi ami ayo kejì wọlé – ami ayo ìṣẹ́gun! 2-1!
Pẹ̀lú kaadi pupa, pẹ̀lú ẹ̀tẹ́ mẹ́wàá, wọ́n ṣì tẹ Chelsea lóri, wọ́n sì kó àmì mẹ́ta lọ sílé.
Lóòótọ́, bí wọ́n ṣe ń sọ, “A kì í fi apá kan gbá ẹrù sórí, ṣùgbọ́n tí ọkàn bá le, apá kan á gbá e.” Tottenham ti fi hàn lónìí pé ọkàn líle ju iye agbábọ́ọ̀lù lọ.
