Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Abameta 01, Oṣù Kẹjọ 2026.
*Ìròyìn ayọ̀ ló kún Old Trafford lónìí!
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester United ti fi agbára hàn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ńlá, nígbà tí wọ́n tẹ ẹgbẹ́ Atletico Madrid ti ọmọ Nàìjíríà, Ademola Lookman ń gbá bọ́ọ̀lù fún, lórí mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ami ayo meji si eyookan 2-1, láti gbé ife eye Snapdragon wọlé.
Eré náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjà líle. Atletico wọlé pẹ̀lú ọgbọ́n, wọ́n sì fẹ́ fi hàn pé àwọn náà kì í ṣe ẹgbẹ́ kékeré. Ademola Lookman gbìyànjú púpọ̀, ó ń sáré, ó ń dá àwọn àyè sílẹ̀, ṣùgbọ́n olùṣọ́ Man U kò jẹ́ kí nǹkan rọrùn fún un.
Nígbà tí gbogbo ènìyàn ń wòye pé eré náà yóò le, Bryan Mbeumo, ọmọ orílẹ̀-èdè Cameroon, dide gẹ́gẹ́ bí akọni!
Mbeumo kọ́kọ́ wọlé kan pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún tó lágbára – gbọò! 1-0 fún Man U!
Atletico dọ́gba, wọ́n sì mú kí eré náà di 1-1, ọkàn gbogbo onífẹ́ Man U bẹ̀rẹ̀ sí í lù gbangba.
Ṣùgbọ́n Mbeumo tún padà wá! Ní ìṣẹ́jú tó ṣe pàtàkì jù, ó tún wọlé kejì pẹ̀lú orí tó mọ́ ọgbọ́n. 2-1! Gbogbo pápá wó lulẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀!
Mbeumo ló gba goolu méjèèjì fún Man U, ó sì di akọni ọjọ́ náà.
Ademola Lookman, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ rẹ̀ pàdánù, gbìyànjú dáadáa, ṣùgbọ́n ayọ̀ ọjọ́ òní kì í ṣe ti Atletico.
Bayi, ife Snapdragon ti wá sí Old Trafford, àwọn ọmọ United sì ń kọrin ayọ̀!
