ADEMOLA ADELEKE WỌLÉ Ẹ KEJÌ, LOBA FÌDÍ ÀWỌN ALÁTAKÒ RẸ JANLẸ

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú, 16, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

*Adeleke tún wọlé – O bori pẹlu Eedegbeta ìbò (511,067)

 

INEC sọ pe Adeleke bori pẹlu ibo to le ni ẹẹdẹgbẹta o le mọkan-din-logoje (511,067), eyi ti o fi bori awọn alatako rẹ patapata.

 

Kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn ti idibo naa waye, Adeleke bori ni ijọba ibilẹ mọkandinlogun (19), nigba ti Bola Oyebamiji to ṣe ipo keji bori ni ijọba ibilẹ mọkanla (11).

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

Ọwọ ọlọpaa tẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin ẹgbẹ́ òṣèlú Accord tí wọn ba káàdì ìdìbò àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oludibo to kò pamọ…

Rà káàdì ìpè rẹ tàbí kí ó sanwó sórí DStv tàbí Gotv rẹ, bẹẹ losi lè sanwó iná sórí Prepaid meter rẹ pẹlu irọrun tí ó ní ìdíyelé alai lẹgbẹ. Tẹ asopo yìí kì ó raa pẹlu irọrun lọdọ wá..

Giwa agba Fasiti apapọ ti Oye-Ekiti, Ọjọgbọn Joshua Ogunwole, to jẹ Alakoso eto idibo naa lo kede Adeleke ni deedee agogo meje kọja iṣẹju mẹrinlelogun (7:24pm) ọjọ Aiku, lẹyin akojọpọ gbogbo ibo ti awọn araalu dibo kaakiri Ipinlẹ Ọṣun.

 

Awọn ijọba ibilẹ ti Adeleke jawe olubori ni: Ariwa Ede, Guusu Ede, Ejigbo, Iwo, Egbedore, Ariwa Ife, Ila-Oorun Ife, Aarin-Gbungbun Ife, Oriade, Ifelodun, Orolu, Ayedaade, Ayedire, Odo-Otin, Boluwaduro, Iwọ-Oorun Ilesa, Ifedayo, Osogbo ati Ila.

 

Oyebamiji lo gba oroke ni awọn ijọba ibilẹ bii Irewole, Isokan, Olorunda, Ila-Oorun Atakumosa, Iwọ-Oorun Atakumosa, Ila-Oorun Ilesa, Boripe, Irepodun ati Obokun.

 

Alakoso eto idibo naa, Ogunwole ninu ọrọ rẹ sọ pe:

“Lẹyin ti Ademola Nurudeen-Jackson Adeleke ti ṣe awọn ohun amuyẹ labẹ ofin, mo wa kede rẹ gẹgẹ bi oludije to jawe olubori nibi eto idibo gomina to waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, to si tun pada sipo naa fun igba keji.”

Lati igba naa ni oniruuru ọrọ ti n jade lori bi Adeleke ṣe wọle sipo gomina lẹẹkeji. Nigba ti awọn kan n ki i ku oriire, awọn miran n pe fun iwadii lẹkunrẹrẹ lori eto idibo naa.

 

Idi niyi ti OJB News Yoruba ṣe ṣe akojọpọ ero awọn araalu nipa abajade idibo naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.