Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Abiolu, Abẹ́òkúta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aiku, 18, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ariwo nla ti bẹ silẹ nínú oṣelu ipinlẹ Ogún, bí Baálè ìlú Olorunsogo, Ilara, ni Ijọba Ibile Imeko-Afon, Oloye Topa Olusegun Peter, ṣe fi ẹ̀sùn kan Alaga ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni Imeko-Afon, Ramoni Adebolu, ati awọn oloye APC miran.
Bẹẹ lo kigbe pe awọn kan lo orukọ òun laimọ gẹgẹ bi oludije ipo Gomina labẹ ẹgbẹ PDP fun idibo ọdun 2027.
Oloye Topa, to jẹ oloye pataki ninu ẹgbẹ òṣèlú PDP, ó sọ eyi ninu apejọ ti o pe awọn oniroyin ni Abeokuta ni ọjọ Satide, Ọjọ kẹtàdínlógún 17, Oṣu Kẹwa, Ọdun 2026.

Kini Oloye Na Sọ?
Baale naa taku pátápátá pe oun ko ra fọọmu Gomina rárá nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party PDP.
Ninu ọrọ tirẹ, o sọ pe:
“Ó bá mi lójijì, o si jẹ́ nǹkan iyalẹnu fún mi lati ri orukọ mi ninu iwe iroyin gẹgẹ bi oludije Gomina labẹ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Mo ti sọ ṣáájú mo sì tẹnumọ lẹẹkan si pe mi o ra fọọmu Gomina, mi o fọwọ́ si iwe kankan pe mo fẹ dije, bẹẹni mi o fun ẹnikẹni ni aṣẹ lati ṣe bẹ ni orukọ mi.”
O tun dárúkọ agbẹjọro kan ti a sọ pe o kọ lẹta si INEC ni orukọ rẹ. Agbẹjọro naa ni Anderson Asemota ti Neplus Ultra Attorneys, ẹni ti a sọ pe o fun INEC ni wakati mejidinlaadota lati fi orukọ Topa si ori atopọ oludije.
Oloye Topa ni: “Mi o ti pade agbẹjọro naa ri, mi o fun un ni aṣẹ kankan.”

Ẹsun Lodi Si APC
Ninu apejọ naa, Baale naa fi ẹsun kan Alaga egbe APC ni Imeko-Afon, Ramoni Adebolu, ati awọn oloye APC miran.
O sọ pe wọn pe oun ni ilu Ilara, wọn sọ pe wọn ni ipo kan fun oun labẹ PDP. O ni oun kọ. Ṣugbọn lẹhinna ni orukọ rẹ bẹrẹ si jade ninu iwe iroyin gẹgẹ bi oludije.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, nigba ti o pe Adebolu lati beere, “Adebolu sọ fun oun pe ki ń fi ara balẹ, ti o si ṣeleri àwọn nǹkan mèremère fun mi bí owo, ọkọ ayọkẹlẹ, ati ipo nla lẹhin ti Senator Solomon Adeola (Yayi) ba wọlé gẹgẹ bi oludije Gomina APC.
O tẹnumọ pe oun ko gba owo kankan lọwọ wọn.

KÍNNÍ ÌDÍ TI ỌRỌ RẸ FÍ SE PÀTÀKÌ ?
Iwadii OJB News Yoruba ri pe wahala yi bẹrẹ lẹhin ti INEC yọ orukọ oludije PDP gidi, Hon. Ladi Adebutu, kuro ninu atopọ awọn oludije ti wọn gbe jade ni October 10, 2026. Eyi lo mu ki ọpọlọpọ awọn lẹta oriṣiriṣi bẹrẹ si lọ si INEC lati ọdọ awọn ti wọn n sọ pe àwọn ni oludije PDP.
Oloye Topa sọ pe Adebutu ni oludije kan ṣoṣo ti o jade ni May 24, 2026, níbi idibo ti oun tikararẹ ṣe àbójútó rẹ.
O tun rọ awọn ajọ alaabo lati wọle si ọrọ naa, nitori o n bẹru nipa aabo ẹmi oun ati idile rẹ, o si rọ INEC lati foju fo gbogbo iwe ti wọn ba mu wa ni orukọ oun.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
AKIYESI PATAKI LATI ODO OJB NEWS YORÙBÁ (DISCLAIMER):
Iroyin yii da lori apejọ oniroyin ti Oloye Topa Olusegun Peter pe n’ilu Abeokuta ati awọn atẹjade ti awọn ile-iṣẹ iroyin nla bi Daily Post, Tribune ati Platform Times ti gbe jáde sẹ́yìn.
Awọn ẹsun ti Baale fi kan Alaga APC, Ramoni Adebolu, ati agbẹjọro Anderson Asemota jẹ ẹsun ti a ko tii jẹrisi pé ó fìdí múlẹ̀. Titi di akoko ti a fi n gbe iroyin yii jade, a ko tii gbọ esi lati ọdọ Ramoni Adebolu, lati ọdọ agbẹjọro naa, ati lati ọdọ INEC.
OJB News Yoruba ti ṣetan lati gbe esi wọn jade ni kete ti wọn ba dahun.
Ẹ tẹle wa fun atẹle iroyin naa.
OJB NEWS YORÙBÁ| ÌRÒYÌN ÀWÙJỌ| ÌRÒYÌN ÒTÍTỌ́
#Ogun2027 #OJBNewsYoruba #ImekoAfon #IroyinOselu

One thought on “Ogun 2027: BAÁLÈ ÌLÚ OLORUNSOGO F’ESUN KÁN APC LORI B’ORUKO RẸ ṢE JÁDE BI OLUDIJE PDP FÚN IPO GÓMÌNÀ”