Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olori Hafsat Temitope Lawal, Èkó | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Abameta, , 17, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Ẹgbẹ́ to n polongo àti tita àwọn àwo onkorin lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ẹgbẹ́ Music Advertisement Association of Nigeria [MAAN] ti fi ìkéde síta fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ wọn káàkiri orile-ede Naijiria, nínú atejade tí Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Dókítà Surajudeen Adewale Amusat tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Hazraj fi síta to tẹ wá lọ́wọ́ lo ti ránṣẹ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Nínú àtẹjáde kan tí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè ẹgbẹ́ náà, Comrade Dr. Surajudeen Adewale Amusa [Hazraj Muzik] fọwọ́ sí, ó rọ gbogbo àwọn Alákóso Ìpínlẹ̀ àti àwọn National Coordinators pé kí wọ́n rí i dájú pé gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ yálà àwọn tó wà nínú àwọn WhatsApp Group wọn forúkọ sílẹ̀ àti àwọn tí kò sí nínú àwọn ìkànnì ẹlẹgbẹ je gbẹ náà kò pá níbi iforukosile òun.

Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ:
“Ìforúkọ sílẹ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an. Wọ́n ti sọ fún wa pé àwọn tí wọ́n bá forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú link yìí nìkan ni a ó mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ gidi ti MAAN, àti pé àwọn náà nìkan ni yóò sì jẹ àǹfààní láti inú ẹgbẹ́ náà.”

ÀKÓKÒ TÍ Ó WÀ:
Ẹgbẹ́ náà fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ ní Ọ̀SẸ̀ KÀN péré láti parí ìforúkọ sílẹ̀ yìí. A rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ pé kí wọ́n fi orúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ ìwé ìforúkọ sílẹ̀ wọn kì wọn ó sì tẹle ìtọ́ni náà dáadáa, kí óruko àwọn tí ó ṣe iforukosile náà bí ó ti ṣe tọ ó máa baà yọ dànù lẹgbẹ.
Ààrẹ Surajudeen Adewale Amusat Hazraj Muzik ro gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ kí a fi orúkọ silẹ bí a ti ṣètò rẹ, torí eyii jẹ́ Imugbooro ọtun àti ọna ikopa sì imọ ẹ̀rọ ìgbàlódé, gẹgẹ bí a ṣe ṣe ìlérí rẹ ṣáájú fún gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ MAAN lapapọ.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
LINK FÚN ÌFORÚKỌ SÍLẸ̀:
Ẹ tẹ link yìí láti forúkọ sílẹ̀ nísinsìnyí:
https://surveyheart.com/form/6ac94765bef3d743c1c2433a
A rọ gbogbo àwọn olórí ẹgbẹ́ ní orílẹ̀-èdè náà láti ṣiṣẹ́ kára kí gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ lè forúkọ sílẹ̀ kí àkókò tó wà má baà kọjá.
OJB News Yorùbá

One thought on “Ìgbà Ọtun ti dé: ÀÀRẸ ẸGBẸ́ MAAN RỌ GBOGBO ỌMỌ ẸGBẸ́ LÁTI F’ORUKỌ WỌN SILẸ”