JIDE KOSOKO ÒNÍ TÍÁTÀ NÍ MI O FẸ KÙ, BÓ TÍ Ẹ JẸ PÉ MO PÀDÁNÙ OWO MILIONU, T’AISAN GBÉ AGO ARÁ MI DE FÚN ỌGBỌ́N ỌDÚN

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje, 19, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

Pe Arike’s and More gẹgẹ bi alase oúnjẹ ìgbàlódé fún òde àríyá rẹ

 

Gbajugbaja àgbà ọ̀jẹ̀ àti olùdarí ère ni agbo Nollywood ilẹ̀ wá nnì, Prince Jide Kosoko ló ti sọ ìrírí àti ìdààmú tí ó ń bá fínra fún odidi ọgbọ́n ọdún gbáko àti bí ó ṣe pàdánù obitibiti milionu owó náírà lórí iṣẹ to yàn láàyò.

 

Se bí a bá kúkú ń rí àwọn ilumoka oṣere, ayọ̀ àti ẹrìn ojú wọn lan rí, a kii mọ irufẹ ogún ti wọn n ja ni ìkòkò àti àwọn òun ìdààmú tí wọ́n ńlá kọjá lai lè pariwo síta fẹ́’nìkan

 

Èèyàn kàn to laami laaka ni agbo Nollywood ni , Prince Jide Kosoko, ti tu àṣírí ọkàn rẹ̀ jáde nípa ìrìn àjò ayé rẹ̀ tó le gan-an tó sì lágbára.

Prince Jide Kosoko

OGUN ỌGBỌ́N ỌDÚN  PẸ̀LÚ ÀÌSÀN ITO SUGAR

Gẹ́gẹ́ bí Jide Kosoko ṣe sọ, ó ti ń gbé pẹ̀lú àìsàn ìtó sugar (diabetes) fún nǹkan bí ọgbọ́n ọdún.

 

Ó sọ pé bí ó ti ẹ jẹ pe òun ó fẹ́ kú, lòun ṣe wọ ìjàkadì pẹlu àìsàn ìtó suga fún ọgbọ́n ọdún, ó wá rọ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú iṣẹ́ eré pé kí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò ara wọn, kí wọ́n máa lọ sí ilé ìwòsàn ní àkókò, kí ọ̀rọ̀ má ba a burú jù.

Kò sai fikùn pé nítorí pé ògo kò ní ìtumọ̀ kankan tí ìlera bá ti bàjẹ́.

 

Ó PÀDÁNU OWÓ TÓ LÉ LÓRÍ ₦300 MILLION NÍNÚ FÍÍMÙ KAN

Jide Kosoko tún sọ pé ó ti fi owó tó lé ní ₦300 million sínú iṣẹ́ fíímù kàn ri, tí owó náà kò sì ní ìtumọ̀ kánkán, kò sì ojú owó débi ère pẹlu.

 

Ohun tó yanilẹ́nu ni pé dípò kí ó máa dá ẹlòmíràn lẹ́bi, òun fúnra rẹ̀ gba pé àwọn ìpinnu kan tí òun náà mú ló fa àdánù náà.

 

Ẹ fojú inú wo bí ẹni tí ó ti lo gbogbo ayé rẹ̀ láti kọ́ iṣẹ́ eré ṣe kó gbogbo owó rẹ̀ sínú iṣẹ́ kàn ṣoṣo, tí owó náà sì pòórá lai ni ère kánkán nínú.

Gbajugbaja oṣere Nollywood ilẹ̀ wá nnì Prince Jide Kosoko

“ÀWỌN ỌMỌ MI LÓ YÉ IPÒ TÍ MO WÀ”

Ipá tó ka ọkàn jùlọ pẹlu àánú ni àwọn ọmọ rẹ̀ kò.

Ó sọ pé ọmọ rẹ̀bìnrin, Sola Kosoko, ti ń ràn òun lọ́wọ́ pẹ̀lú owó láti ìgbà tí kò tíì wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga.

Fún bàbá láti sọ bẹ́ẹ̀ ní gbangba, ó nílò ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn gidi.

Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ fún itọju àti afarada lásìkò ìlà kọjá re, tí wọn sì dúró tì í ní àsìkò ìṣòro.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:

Eyii ni bí Baálè ìlú Olorunsogo ni imoko afon ṣe fi ẹ̀sùn kàn àwọn olóyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC lórí bí orúkọ rẹ ṣe hàn bí oludije sípò gomina ipinlẹ Ogún lábẹ́ òṣèlú PDP. *O ni wọn ṣèlérí òun mèremère bí owó, ọkọ àti àwọn nǹkan mìíràn bí Yayi bá ti wọlé ìbò tán, ṣùgbọ́n òun ó gba a lọ́wọ́ wọn…

Gbogbo nnkan ni yóò padà di ìtàn, ọjọ ńlá ọjọ mani gbàgbé ni ọjọ ti Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu fojú wí ina òfin tí ó sún sseli Ọlọpa, nibo lẹ́yìn ń gbé nibo lẹ́yìn wá lọdun náà lọhun..

Ẹ̀KỌ́ NÍNÚ ÌRÒYÌN YÌÍ

Ìtàn yìí fi hàn pé àwọn gbajúmọ̀ tí a ń yìn jẹ́ ènìyàn bí wa. Lẹ́yìn ẹ̀rín wọn, àìsàn wà, àdánù owó wà, ìrubọ ìdílé wà, àti òru tí gbogbo ayé kò mọ̀.

 

A gbadura pé Ọlọ́run yóò tẹ̀síwájú láti fún Prince Jide Kosoko ní agbára, yóò dáàbò bo ayé rẹ̀, yóò fún un ní ìlera pípé, yóò sì bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n dúró tì í ní àsìkò ìṣòro.

 

Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún Nollywood fún ọ̀pọ̀ ọdún, a fẹ́ kí ó jẹ èrè iṣẹ́ rẹ̀.

 

Ní èrò yín, apá wo nínú ìtàn rẹ̀ ló ka ọkàn yín jùlọ? Ìjà rẹ̀ pẹ̀lú àìsàn ìtó sugar fún ọgbọ́n ọdún, àdánù owó ńlá náà, tàbí ìfẹ́ àti ìrubọ àwọn ọmọ rẹ̀? Ẹ sọ fún wa ní comment.

 

#OJBNewsYoruba #JideKosoko #Nollywood #Ilera

One thought on “JIDE KOSOKO ÒNÍ TÍÁTÀ NÍ MI O FẸ KÙ, BÓ TÍ Ẹ JẸ PÉ MO PÀDÁNÙ OWO MILIONU, T’AISAN GBÉ AGO ARÁ MI DE FÚN ỌGBỌ́N ỌDÚN”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.