Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 1, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Bi ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin Ominira Naijiria ṣe ku ọjọ diẹ, Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti rọ awọn ọmọ orilẹ-ede lati ma ṣe sọ ireti nu lori Naijiria, o ni diẹ naa lo ku ki orilẹ-ede yii de ibi giga rẹ.[66]
Abẹnugan Ile-igbimọ Aṣoju, Olori Tajudeen Abbas, to ṣoju fun Aarẹ Tinubu nibi irun Jimọ pataki ti wọn ki ni Mọṣalashi Ijọba Apapọ ni Abuja lọjọ Ẹti, lati ṣami ayẹyẹ ọdun kẹrindinlaadọrin Ominira Naijiria, lo sọ ọrọ naa.

“Naijiria ti wa loju ọna, O láti de ibi giga”
Ninu ọrọ Aarẹ Tinubu ti Abbas gbe kalẹ, o ṣalaye pe orilẹ-ede Naijiria ti wa loju ọna to tọ, biotilẹjẹpe ko ti i si ibi ti o yẹ ko wa patapata lọwọlọwọ.
O rọ araalu lati tẹle atunṣe ti ijọba rẹ n ṣe, ki Naijiria le de ilẹ ileri rẹ.
“Ọdun kẹrindinlaadọrin ti Naijiria pe yii fi han pe agba ti de, bo tiẹ jẹ pe bi a ba wo bi a ṣe n ba a ṣe, nnkan ko ṣe daadaa.
Ọlọkan-o-jọkan aburu lo koju Naijiria nigba kan ri, bẹẹ si ni orilẹ-ede yii padanu ọpọlọpọ anfaani to pọ.
ÌRÒYÌN ISAAJU:
Amọ a dupẹ lọwọ Ọba Allah Alagbara to fun wa ni ẹmi ati alaafia lati ri ayajọ yii ninu itan loni.”
Bẹẹ ni Abbas to gbẹnusọ fun Tinubu wi.
“Ẹ Fun Tinubu Lanfaani Lati Tẹsiwaju Ninu Atunṣe Rẹ”
Ni itẹsiwaju ọrọ naa, Abẹnugan Ile-igbimọ Aṣoju naa sọ pe:
“Iṣẹ ti mo fẹ jẹ lorukọ Aarẹ fun orilẹ-ede yii ni pe ki ẹyin eeyan ma sọ ireti nu.

Alaafia n pada bọ sori ilẹ yii. Idagbasoke n pada bọ sori ilẹ yii. Nnkan yoo pada daa bi a ṣe n ba tiwa-n-tiwa lọ.”
O fi kun un pe ki araalu ma ṣe wo aṣiṣe ti o ti wa kọja, tabi anfaani ti Naijiria ti sọnu, bikoṣe ki wọn maa wo atunṣe ti Tinubu n ṣe lọwọlọwọ.

Abẹnugan naa wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati jẹ ki Aarẹ Tinubu pari iṣẹ ti o bẹrẹ.
O ni ki wọn fun un ni anfaani lẹẹkan si i, nitori awọn ọmọ Naijiria paapaa ti farajin pupọ, asiko si ti n bọ lati jẹre ifarajin wọn gẹgẹ bi o ṣe sọ.

One thought on “Ẹ MA SỌ ÌRÈTÍ NU, DÍẸ̀ LOKU KI NÀÌJÍRÍÀ DE IBI GÍGA – Ààrẹ Tinubu pàrọwà fún ara ìlú”