Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olawale Dada, Ilorin | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 17, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Pẹ̀pẹ́yẹ pamọ́ lode Ilorin lónìí ní ilé ẹjọ́ kan nílu Ilorin nígbà tí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ tó wà láàrín Àràkùnrin Afeez Adegbola tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Tani Olóhùn àti àwọn Alakatakiti Ẹsin Musulumi (Islamic Defense Group) wáyé.

Nínú ẹjọ́ náà, agbẹjọro Tani Olóhùn, Barrister Mufutau Olufola Olobi-Kojale, sọ pé ẹgbẹ́ ọ̀hun kò tẹ̀lé òfin nípa bí wọ́n ṣe pe oníbàárà òun lọ sí ilé ẹjọ́. Ó ní wọn kò fi ìwé ìpè ilé ẹjọ́ (Court Invitation Letter) ránṣẹ́ sí i lọ́nà tó tọ́.
Barrister Mufutau sọ pé dípò kí wọ́n fi ìwé náà ránṣẹ́ sí oníbàárà òun, ni wọ́n lọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára láti fi ìkéde síbẹ̀. Ó ní èyí kò bá òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mu rárá.

Ó tẹ síwájú pé, bí wọ́n bá sọ pé wọn kò mọ ilé oníbàárà òun, ṣé ilé rẹ̀ náà ni wọn lọ ká mọ̀ tí wọn fẹ́ jígbé lọ ní ọjọ́ tí Olóhun bá ti dẹ́rú àti jámbá wọn jẹ? Ó ní títí di òní yìí, wọn kò tíì fi ìwé pe oníbàárà òun tàbí kí wọn lẹ ìwé mọ́ ara ilé rẹ̀ lọ́nà tó tọ́.

Agbejọro naa sọ pe wahala ṣẹṣẹ bẹrẹ ni. Ó ní ilé ẹjọ́ ńlá (High Court) nìkan ló ní agbára láti gbọ́ ẹjọ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ilé ẹjọ́ kékeré ní Ilorin kò ní àṣẹ láti gbọ́ ọ.
Ó fi kún un pé Tani Olóhùn kò pa ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kò ṣe fàdìyà. Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan oníbàárà òun kò lẹ́sẹ̀ nlẹ̀. Ó ní Tani Olóhùn jẹ́ ẹni tí ó ń jẹ Ifá Akíbarú, ìjà si ṣẹṣẹ bẹrẹ lode Ilorin.
Orisun: OJB News Yorùbá

Omo je omo kwara ni ifelodun ni oke ode omo bibi ile igbomina omo yoruba atata olorun ko ni ba isese je o amin ase
Àmín àṣẹ Edumare óò