Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọbọ, 17, Oṣù Kẹ̀sán 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Sẹ́nátọ̀ Solomon Adeola (APC, Ogun West), olùdíje fún ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn lábẹ́ ẹgbẹ́ All Progressives Congress, ti halẹ̀ pé òun yóò fi Hon. Abayomi Hunye, ọmọ ẹgbẹ́ APC tí wọ́n ti dá dúró láti Tube, Ipokia LGA, àti Ambassador Folake Marcus-Bello ti ẹgbẹ́ PDP lẹjọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti irọ́ tí wọ́n sọ ní orí tẹlifíṣọ̀nụ orílẹ̀-èdè nípa òun àti ìdílé rẹ̀.

Hunye àti Marcus-Bello ti sọ̀rọ̀ lórí ètò Channels Television níbi tí wọ́n ti sọ pé Sẹ́nátọ̀ Adeola jẹ́ ọmọ bibi Ìpínlẹ̀ Èkìtì àti àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn mìíràn láìsí ẹ̀rí kankan.
Nítorí náà, Sẹ́nátọ̀ Adeola ti fún wọn ní wákàtí mẹ́rìnlélógún (24 hours) láti fi ẹ̀rí ọ̀rọ̀ wọn nípa ìpìlẹ̀ rẹ̀ jáde ní gbangba tàbí kí wọ́n múra sílẹ̀ fún ẹjọ́ lórí irọ́ àti ẹ̀gàn tí wọ́n tàn kálẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀nụ tí ó sì tàn kálẹ̀ lórí àwọn ìkànnì ìròyìn mìíràn.

Gẹ́gẹ́ bí Sẹ́nátọ̀ náà ṣe sọ:
“Mo wò ó pẹ̀lú ìyàlẹ́nu bí àwọn ènìyàn tí èmi kò mọ rárá ṣe ń sọ irọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nípa ìpìlẹ̀ mi láìsí ẹ̀rí kankan. Ọ̀kan sọ irọ́ pé mo wá láti Èkìtì, nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbo gangan ní Èkìtì, kò lè dáhùn. Èkejì náà ń purọ́ nípa ibi tí a sin àwọn òbí mi sí bí ẹni pé òun wà nínú àwọn tí ó sin wọn, gbogbo rẹ̀ láti dá irọ́ tí kò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ láre. Ó tó bẹ́ẹ̀. Wọ́n gbọ́dọ̀ mú ẹ̀rí wọn jáde láàrín wákàtí mẹ́rìnlélógún tàbí kí wọ́n múra sílẹ̀ fún ẹjọ́ mi”
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Ao rántí pé iróyin nípa pé Sẹ́nátọ̀ náà jẹ́ ọmọ bibi Èkìtì ni wọ́n ti kọ́kọ́ lò gẹ́gẹ́ bí ètò ìpolongo láti dẹ́na kí ó má ba di Sẹ́nátọ̀ tó ń ṣojú Ogun West, ṣùgbọ́n ètò náà kò ṣiṣẹ́ nítorí pé àwọn ènìyàn agbègbè náà dibo fún un lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ìdìbò 2023. Ìjíhinde irọ́ yìí jẹ́ nítorí bí ó ṣe ń lọ síwájú láìdáwọ́dúró fún ìdíje Gómìnà 2027 ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.
Gẹ́gẹ́ bí Olóyè Kayode Odunaro to jẹ Olùdámọ̀ràn lórí iṣẹ́ ìròyìn fún Sẹ́nátọ̀ Adeola CON. Ṣe fi ọwọ sì

One thought on “Nítorí ẹsun èké: YAYI FẸ PÉ HUNDEYIN ÀTI MARCUS LEJO”