Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Daniel Ayomiposi Oluwamuyide, Sango-Ọta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́rú, 26, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
Ni agogo mẹjọ owurọ ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun 2026, awọn ọlọpa apakan Mowe ti Ipinlẹ Ogun tú ilé iṣẹ aṣiri kan ti wọn n ta ọmọ ní Abule Abaren, lẹba Toluwalase Street, nipasẹ Gbarinmole, Mowe.
Gege bi alukoro ọlọpa Ipinlẹ Ogun, ASP Oluborode Opeyemi ṣe sọ ninu atẹjade rẹ, iṣẹ yii jẹ abajade oye ti wọn ti n gba fun igba pipẹ lori ẹsun jijakadi ọmọ ati gbigbe ọmọ lọ sibi ti ko tọ.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
AWỌN TI WỌN GBA LÁ:
Obinrin meji ti o loyun pupọ: Ilesanmi Foluke ọmọ ọdun mejilelogun ti o loyun oṣu meje, ati Ejekwa Melody ọmọ ọdun ogun ti o loyun oṣu mẹjọ
Ọmọ mẹrin: Ọmọkunrin meji ati ọmobinrin meji
AWỌN TI WỌN MU:
Ọlọpa mu eniyan mẹfa ti wọn fura si:
*Florence Glory Ogbona – 58 ọdun
*Magdalene Julius – 63 ọdun
*Chidike Egwuonwu – 40 ọdun
*Onyechu Chidike – 35 ọdun
*Stephen Ogbona – 39 ọdun
*Oseni Kusamotu Idaya – nọọsi to n tọju wọn

OHUN TO TUN ṢẸLẸ:
Lẹyin igba ti wọn tú ilé naa, ọlọpa tọpasẹ lọ si ile-iwosan kan ni Mowe, nibiti obinrin miiran ti a pe ni Blessing Bright Effiong ọmọ ọdun mẹrindinlogbon ti bimo ọmọkunrin ni ọjọ ogun oṣu kẹjọ.
Sugbon nigba ti wọn de, wọn ko ri ọmọ ọwọ tuntun naa. Idi niyi ti wọn fi mu nọọsi naa lati wa ọmọ naa.
Kọmiṣana ọlọpa Ipinlẹ Ogun, Bode Ojajuni, yin awọn ọlọpa Mowe fun iṣẹ daadaa, o si ni wọn yoo gbe ẹjọ naa lọ si SCID Eleweran, Abeokuta fun iwadii siwaju.
O ni: “A o tẹsiwaju lati ja jijakadi ọmọ ati tita ọmọ ni Ipinlẹ Ogun.”
ERO TÍWÁ:
Ẹjọ ile ti wọn ti ń tà ọmọ yii kii ṣe tuntun ni Ogun. Ṣugbọn eyi ti o wa ni Mowe fihan pe awọn oniṣẹ buruku yi n lo ile ti ko pari lati fi pa awọn obinrin alaini ti o loyun mọ. Wọn maa n bẹ awọn ọkunrin lati fún wọn loyun, lẹhin naa wọn a ta ọmọ naa.
Awọn olugbe Mowe, Ofada, ati gbogbo Ipinlẹ Ogun gbọdọ ṣọra. Ti ẹ ba ri ohun ti ko tọ, ẹ jẹ ki ọlọpa mọ ni kiakia.
OJB NEWS YORÙBÁ – ITAN, ISORO, IGBODO, IMOLE
