Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Abike Esther Serena, Sango-Ọta| Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Aje, 17, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410
*Gbajumọ iṣẹ orin kíkọ rẹ kì àwa náà o dojú kọ òṣèlú tí wá, Demola Faleke dá padà fún Davido
Ìjà ọ̀rọ̀ ti bù jáde láàrín olórin Afrobeats tó gbajúmọ̀ jùlọ, David Adeleke (Davido) àti ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó ń ṣojú Ikeja Federal Constituency, Hon. James Abiodun Faleke, lẹ́yìn ìdìbò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tó wáyé ní Ọjọ́ Abámẹ́ta 15, Oṣù Kẹjọ 2026.
Kí ni Davido sọ?
Davido, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ abúrò sí Gómìnà Ademola Adeleke, ti kọwé sórí ìkànnì ayélujára X ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta, ó ń ké sí Faleke pé kó bọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ àwọn ará Ọ̀ṣun, kó sì má ṣe fi titẹ gba INEC lọ́wọ́ láti yí àbájáde ìdìbò náà padà. Davido ń ṣe atilẹyin fún àbúrò bàbá rẹ̀ tó ń díje lábẹ́ ẹgbẹ́ Accord Party.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Èsì Faleke:
Ní Ọjọ́ Àìkú, Hon. Faleke fèsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lórí X. Ó sọ pé:
“Mo kò lè ní ipa lórí INEC. Mo kò tíì ṣe rìgì ìdìbò rí ní gbogbo ìgbà ayé mi nínú òṣèlú. Kí Davido dojúkọ orin rẹ̀, kí àwa náà dojúkọ òṣèlú wa.”
Faleke, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí ńlá nínú ẹgbẹ́ APC tí ó ṣe atilẹyin fún Bola Oyebamiji, sọ pé INEC jẹ́ ilé-iṣẹ́ olómìnira, kò sí ẹnikẹ́ni tó lè pa á lásẹ láti yí àbájáde padà.
Ìdìbò náà ti parí bayii, INEC sì ti kéde Ademola Adeleke gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí, Gómìnà Adeleke náà sì ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Bola Tinubu pé ó jẹ́ kí ìdìbò náà jẹ́ èyí tí ó mọ́ tónítóní.
Ọ̀rọ̀ yìí ti mú ariwo ńlá wá lórí ayélujára, nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn rò pé olórin kò gbọdọ̀ dara pọ̀ mọ́ òṣèlú, àmọ́ Davido tẹnumọ́ pé òun kò ní jẹ́ kí a ṣe àdáwọ́dá sí ìfẹ́ àwọn ará Ọ̀ṣun.
OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀lé ìròyìn yìí.
