*Kìí ṣe Olóòlù fúnra rẹ̀ ló rí, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni, a sì ti ṣètútù fún un – Ó ní òun yóò máa sá kúrò níbàdàn bí ọdún Olóòlù bá ń bọ̀
Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Bolarinwa Wasiu, Ọṣun | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Iṣẹgun 4,, Oṣù Kẹjọ 2026.
Ìròyìn tí ó ń fò sókè láti hi ọ̀sẹ̀ diẹ sẹ́yìn kè ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn pé ọmọgẹ Wasilatu, ọmọbìnrin tí wọ́n lọ rí Eégún Olóòlù ní Ìbàdàn tí kú, kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Òótọ́ ni pé ọmọgẹ náà wà láyé, tí ó sì wà ní àlàáfíà.
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwo Isọlá Gbọláhàn Akéèm, akọ̀wé ilé Eégún Olóòlù, sọ nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Wasilatu lónìí.
GẸ́GẸ́ BÍ OLÚWO ṢE WÍ :
“Kò sí òótọ́ nínú pé Wasilatu ti wọ́n lọ rí Eégún Olóòlù ti kú. Ó wà láyé. Lóòótọ́ ni pé ó ṣe ohun tí kò yẹ, ṣùgbọ́n a ti ṣe àtúnṣe rẹ̀.”
Olúwo Isọlá fi kún un pé, nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe, ó yé wọn pé kìí ṣe Eégún Olóòlù fúnra rẹ̀ ló fojú kan Wasilatu tàbí tí ó ya fídíò rẹ̀. Àwọn èrò tí wọ́n ń tẹ̀lé Eégún Olóòlù ni wọ́n ṣe ìwà náà.
Ó wá sọ pé Wasilatu fúnra rẹ̀ ti jáwọ́, ó sì ti sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí. Ó ní nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀, ibínú àwọn èèyàn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fẹ́ yá wọlé sí ilé Wasilatu láti lù ú, ṣùgbọ́n Olóòlù àti àwọn àgbà ilé ti ṣe ìrẹ́pọ̀ àti ìrápadà fún un gẹ́gẹ́ bí àṣà ìbílẹ̀ ṣe là.
Láti ẹnu Wasilatu fúnra rẹ̀, ó ní ẹ̀kọ́ ńlá ni ó ti kọ́. Ó sì ṣe ìlérí pé láti ìsinsìnyí lọ, bí ọdún Olóòlù bá ti ń bọ̀, òun yóò máa sá kúrò ní Ìbàdàn, kí ó má baà tún ṣe àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Olúwo náà rọ àwọn ọ̀dọ́, pàápàá jùlọ àwọn tí wọ́n ń lo fóònù láti máa ya fídíò, láti bọ̀wọ̀ fún àṣà àti ìṣe àwọn àgbà, nítorí pé àṣà ni ẹ̀wọ̀n ìṣe.
OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀lé ìròyìn náà.
