Orísun: OJB News Yoruba | Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Iṣẹgun 4,Oṣù Kẹjọ 2026.
Ìyàlẹ́nu lọ́jọ́ ló gbà àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, nígbà tí wọ́n rí òṣèré gbajúmọ̀ àti olóṣèlú Desmond Elliot nínú Africhatta Film Village tí gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá, Ibrahim Chatta kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó wà níbẹ̀ ṣe sọ, Desmond Elliot tí ó ti pẹ́ tí kò ti kópa nínú fiímù nítorí iṣẹ́ òṣèlú, dé abúlé náà láti pàdé Ibrahim Chatta. Àwọn àwòrán tí ó jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára fihàn wípé méjèèjì ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ní iwájú ilé àtàtà tí ó wà nínú abúlé fiímù náà.
Àwọn èèyàn ti ń sọ pé bóyá ìpàdánù ipò òṣèlú tó ṣẹlẹ̀ sí Desmond Elliot ló mú un rò láti padà sí iṣẹ́ tí ó gbé e ga ní àkọ́kọ́, èyí tí í ṣe eré ṣíṣe. Títí di ìsinsìnyí, Desmond kò tíì sọ ohunkóhun, ṣùgbọ́n àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ń yọ̀ pé wọ́n tún fẹ́ rí i lórí atẹ fiímù.
Abúlé fiímù Ibrahim Chatta tí ó tó 74 acres tí ó ná ní bí 1.4 Billion Naira láti kọ́, ti di ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré ńlá ń lọ báyìí láti ṣe fiímù ìbílẹ̀.
OJB News Yorùbá yóò máa fún yín ní ìròyìn kíkún bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ń lọ síwájú síi.
