IRO ŃLÁ NIPE OBASANJO ṢIṢẸ FÚN TÍNUBU, PETER OBI LO Ń ṢIṢẸ FÚN LÁTI DI ÀÀRẸ NI 2027 – Osuntokun

Orísun: OJB News Yorùbá | Akọroyin: Esther Abikemi, Abẹ́òkúta | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Aje, 27, Oṣù Keje 2026. 

 

Gbajugbaja olùgbànímọ̀ràn òṣèlú àti ẹni tó sún mọ́ Olóògbé Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Akin Osuntokun, ti fọ́ gbólóhùn àwọn tí ń sọ pé Oloye Olusegun Obasanjo ti darapọ̀ mọ́ Ààrẹ Bola Tinubu.

 

Osuntokun sọ kedere pé gbogbo ọ̀rọ̀ náà jẹ́ irọ́ ńlá àti èrò inú àwọn kan.

 

GẸ́GẸ́ BÍ OSUNTOKUN ṢE SỌ :

“Kò sí òtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ pé Baba Obasanjo ń ṣiṣẹ́ fún Tinubu. Èyí jẹ́ ìròyìn èké. Títí di òní yìí, Baba ṣì dúró gidi lẹ́yìn Peter Obi.”

Ó tún jẹ́rìí sí i pé ète Baba Obasanjo fún ètò ìdìbò 2027 ni kí Peter Obi àti Rabiu Kwankwaso fi ọwọ́ sọwọ́pọ̀ kí wọ́n lè gba orílẹ̀-èdè là.

 

Osuntokun sọ pé Obasanjo gbàgbọ́ pé àjọṣepọ̀ Obi àti Kwankwaso nìkan ni yóò lè mú ìyípadà tí àwọn ọmọ Naijiria ń fẹ́ wá.

 

Ìròyìn pé Obasanjo ti yípadà sí ẹgbẹ́ Tinubu ti ń tàn káàkiri lórí ìkànnì ayélujára ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Osuntokun ti wá fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí i pé kò rí bẹ́ẹ̀ rárá.

 

Kí ni ẹ rò? Ṣé àjọṣepọ̀ Obi àti Kwankwaso yóò ṣẹ́gun Tinubu ní 2027?

 

Ẹ sọ èrò yín ní comment, kí ẹ tẹ Follow OJB NEWS YORUBA fún ìròyìn òṣèlú tó gbóná jùlọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.