Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Olalekan Akanji Ademeto, Abuja | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ́ Àìkú, 4, Oṣù Kẹ̀wá 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

Gbajugbaja Òṣèré Nollywood àgbà, Yemi Solade, ẹni ọdún merindinlaadorin (66 years) , ti fi ẹ̀sùn kan Banki Guaranty Trust Bank (GTB) pé wọ́n yọ ju N18,000 lọ kúrò nínú àkántì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ (service charge) tí kò yé kí wọn yọ.
Nínú ìfìwéránṣẹ́ rẹ̀ lórí Instagram ní ọjọ́bọ̀, òṣèré náà fi risììtì kan tí ó fi hàn pé wọ́n yọ N18,912 hàn, ó sì sọ pé ó yà á lẹ́nu gidigidi.
Ó pè é ní “jibiti àti ìnira”, ó béèrè bóyá àwọn oníbàárà mìíràn náà ti ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀, ó sì rọ wọ́n láti sọ̀rọ̀.
“GTB, lónìí, ní ọjọ́ Ominira Nàìjíríà 66th, ẹ yọ ju N18,000 lọ kúrò nínú àkántì mi ní orúkọ àti àbẹ́ owó iṣẹ́ tí mi ò tíì yé. N18,000 gbáko! Kí ni mo rà lọ́wọ́ yín? Mo ti wà pẹ̀lú yín láti ọdún 1995. Fẹ́rẹ̀ẹ́ N20,000, èé ṣe? Tí ẹ̀sùn yìí bá kan yín, ẹ jẹ́ ká pe GTB níjà.”
Nínú àkọlé rẹ̀, ó tún sọ pé “what an independence robbery” – ìjibiti ọjọ́ ominira.

Ọ̀pọ̀ àwọn gbajúmọ̀ mìíràn dáhùn nínú comment, lára wọn ni Fathia Balogun tí ó sọ pé:
“Gbogbo báńkì ni. Ó dàbí pé wọ́n ń kó aṣeyọrí wọn jọ nípasẹ̀ owó wa.”
GTBank kò tíì dáhùn sí ẹ̀sùn òṣèré náà títí di báyìí.
ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ:
Láìpẹ́ yìí, Solade tún sọ bí wọ́n ṣe san owó fún un láti ṣe bí ẹni pé kò lè rìn gẹ́gẹ́ bí apá kan nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìwòsàn ìyanu tí wọ́n ṣe lágbára ní ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí ó wà ní ilé-ìwé.
OJB News Yorùbá yóò máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ náà.

One thought on “WÀHÁLÀ TÚNTÚN LỌRUN GTB BI YẸMI SOLADE ṢE FẸ̀SÙN KÀN WỌN L’ORI……”