SUNDAY IGBOHO GBÀ TAANI ỌLỌ́RUN KALẸ, NI ILEEṢẸ ỌLỌPA ÌPÍNLẸ̀ ỌYỌ BA ṢÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀

Orísun: OJB News Yoruba | Akọroyin: Muyideen Akinro, Ìbàdàn | Olootu: Lekan Lawal | Ojú-òpó: OJB Media Hub | Ọjọ Iṣẹgun, 25, Oṣù Kẹjọ 2026 | ojbmediashub.com.ng | +2348066952410

 

 

Ọlọpa Ipinlẹ Oyo ti sọ idi ti awọn ọlọpa lati Kwara State fi fẹ mu Abdulazeez Adegbola (Tani Olohun) ni ile rẹ ni Ibadan lana, August 25, 2026.

Gẹgẹ bi alukoro ọlọpa Oyo, DSP Ayanlade Olayinka ṣe sọ ninu atẹjade lana:

 

Awọn ọlọpa Kwara wa lori iṣẹ ijọba gẹgẹ bi warrant ti Upper Ilorin Magistrates’ Court, Ilorin funni, nitori ẹsun pe o le fa ìdàrú àlàáfíà.

Warrant naa jade nitori Tani Olohun ko bọwọ fun bail ti wọn fun un tẹlẹ.

Ẹsun naa ti Ilorin Heritage Preservation Foundation fi sile, wọn sọ pe o ṣe video lori Facebook, YouTube, TikTok ti o fi adura Islam ṣe yẹyẹ, o le fa ija ẹsin.

ÌRÒYÌN ÌṢÁÁJÚ 

Eyii ni ìtàn ìgbésí ayé olóògbé Taiwo Hassan Babatunde Ogogo gbajumọ osere tiata to dára ilẹ̀…

Owo rèé, ikú rèé, ìyàwó l’anloodu fún mi ní faifu millionu kí n fún lóyún apá karùn-ún ìtàn akinkanju ọkùnrin kan nilu Sango-Ọta…..

DRAMA NI IBADAN:

Awọn ọlọpa Mẹ́rin ti wọn wọ plainclothes de ile Tani Olohun ninu ọkọ ti ko ni plate number, wọn si fi i ba ilẹ. Awọn aladugbo kigbe pe “Ajinigbe ni!” wọn si pe Sunday Igboho.

 

Sunday Igboho de pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ, o ba awọn ọlọpa sọrọ, o si pe olori ọlọpa lori foonu. “Ó ní mo ti sọ fún Komisanna Ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara kò máa dá sí ọrọ ẹṣin mọ, Sunday Igboho dá sí ọ̀rọ̀ náà

Awọn alẹyinju aanu la gbọ pe wọn tete ranṣẹ si olori ẹṣọ aabo ibilẹ nni, Iru Ekun, Sunday Adeyemo tọpọ mọ si Igboho lati wa ṣe iranwọ fun Tani Olohun, lori awọn to fẹẹ jii gbe.

 

Ninu fọnran ọhun, ni Igboho tí ni mo ti sọ fún Komisanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara kò máa dá sí ọrọ ẹṣin, eyii lè fa ìjà ẹṣin laarin ìlú, wọn ń jí àwọn èèyàn gbé ní Kwara, wọn ń jí àwọn ọba gbé ẹ ó dà sí eyii, ẹ fẹ́ wàá  gbé èèyàn láti Ìbàdàn lọ sí Ilorin, kò lè ṣe é ṣe o.

 

“Idile mi pe Sunday Igboho, o de lẹsẹkẹsẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ,” orisun kan sọ.

Nigba ti wọn tu u silẹ, aṣọ Tani Olohun ti fa ya, o si joko lori ilẹ o dupẹ lọwọ Igboho, Gomina Seyi Makinde, ati Komisana Ọlọpa.

Àwòrán Taani Ọlọ́run lásìkò tí àwọn Ọlọpa fẹ́ gbé ní tipátipá n’ilu Ibadan

Kọmiṣana Ọlọpa Oyo paṣẹ ki awọn ọlọpa Kwara pada si ipilẹ wọn, ki ẹjọ si lọ si ile-ẹjọ Ibadan gẹgẹ bi ofin agbegbe.

 

Tani Olohun ti wa ni atimọle tẹlẹ ni August 2023 fun ẹsun kanna, wọn si fun un ni bail ni igba mẹrin ni ile-ẹjọ mẹta.

 

OJB News Yorùbá yoo tẹsiwaju lati fun yin ni iroyin.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

OJB MEDIA HUB is a premier online news platform delivering accurate, timely and unbiased new accross Nigeria and the world.